adiitu olodumare€¦ · o di owuro ana ti mo ti fie nu mi ba onje mo, sugbon nko ri ki enyin papa...
TRANSCRIPT
ADIITU OLODUMARE
ADIITU OLODUMARE PADE IJANGBON LONA
NKAN SE
1a. Se apejuwe eni ti o ni ki Adiitu Eledumare lo be
Ogede wa ni oko.
b. Iru Oloye wo ni eni naa
c. Ki ni oruko Baba ati Iya Adiitu Eledumare
d. “O n ni yi, O n ni yi, On ni yi” ki lo fa oro yii ati wipe
tani oro yii nsapejuwe
2a.Iru awon ejo wo ni Anjonnu Ijongbon ro mon Adiitu
Eledumare lese fun awon igi.
b. Daruko awon oniruru eranko afayafa ti Anjonnu iberu
ko jade ninu apo re.
c. Ki ni Adiitu Olodumare ri ti o fi taji loju orun.
d. Tani o so oro yii ati tani o n so oro naa fun –
“Iroko, iwo ni awon omo enia nla se aga, iwo ni nwon
nla se ibusun, iwo ni nwon nla se apoti, iwo ni nwon tun
nfi se posi oku won. Ko si nkan ti nwon ko nfi oju re ri.
Wo eleyi, omo enia, o ko oniruru nkan buruku gbogbo, o
n gbe kiri lati ba fi se ibi. Eru buruku na lo wa lori re yi,
nje mo bi o, o ye ki n pa je tabi ko ye? O ye ki n pa eniti
ngbe ejo oka kiri lati fe se ibi tabi ko ye? O ye ki n pa
eniti ngbe paramole kiri fun ijamba tabi ko ye?
e. Ma bo, iwo ti o wa lori igi, ikun re bamba, ehin orun
re bakimo, ibadi re rapata yio se ipade ninu isasun obe
mi
Tani o so oro yii?
Ta si ni oro naa n bawi
3a. Daruko awon oye ti o wa ni Ilu Ifehinti
b. Ki ni o gbehin ekeji Oba ilu Ifehinti
c. Tania won Yoruba n pe ni abobaku ni ile Yoruba
d. Oruko miran wo ni a n pe abobaku ni ile Yoruba.
4a. Yato si ile Yoruba, orile ede miran wo ni a tun ti le ri
abobaku nigba lailai nile Afirika.
b. Nisisiyi o ti se ase-ma-se, o gbagbe ipo re o si ja sinu
kanga, o si omonikeji re lona, o fi oko oloko fun eni
eleni, Babalawo ilu dajo fun o, Olorise Ilu dajo iku fun
o, Sango ilu dajo iku fun o, Oya ilu dajo iku fun o,
Egungun ilu dajo iku fun o, Oro ilu dajo iku fun o, awon
Oso ati Aje, gbogbo Elebologun patapata, lomode,
lagbalagba, lokunrin, lobinrin ati gbogbo arugbo
porogodo, gbogbo won lo dajo iku fun o. Gegebi ofin wa,
ekeji ilu, ki ori re to kuro lorun re, wi fun ni, tani ki o ku
pelu re?
Tani o so eleyii?
Tani won so sii?
ALABAPADE ADIITU OLODUMARE
1a. Ni ojo ti mo ti nri ehin ti o funfun, nko ri ehin ti o
funfun bi ti okunrin naa ri, ni ojo ti mo ti nri ahon, nkori
eyiti o pon dede bi enipe onje ko da a ri bi tire, ni ojo ti
mo ti n ri oju ti o mole gara, nko ba iru ti okunrin yii
pade ri. Ki a si so pe enia soro o fi oro wu enileyi so,
enia rin lese, o fi irin wu elomiran rin, enia wo aso, o mu
ki a ma wo aso naa kiri, tabi iho ninu eni mo, tabi apa
eni ko gun lasan jawala, tabi omo ika owo ba owo mu,
omo ika ese ba ese mu, ti okunrin naa yato lopolopo.
Tani eniti n soro yii n sapejuwe?
2a. Igba ti ojo naa sip o pupo to bayii, dereba ko ri ibi
iwaju mo, asehinwa asehinbo dereba fa kokoro yo loju
moto, o gbe ese le ibi idaduro oko, oko duro gbonin, o di
ki a ma wa wo oju ara wa. Bi o si tile je pe ati gbogbo
ilekun mo ara wa lori pinpin, ti enikeni ko gbin, ti enia
ko soro, sibe okunrin kan lu moto le wa lori. Okan ilekun
lekini, o kan a lekeeji, o tun kan a lekeeta, a ba silekun a
wo ode”
Tani o n lu moto?
Ki ni oun lu moto si fun
OBIRI AYE ATI IPONJUDIRAN
1a. Ki enia ji, ki kobo se alai ba a ji, ki enia ko aso si ara
ki o dabi jowolo ogede fun akisa, ki odidi ile ojo kan su
lai bu omi si enu, ki enia di eniti o nti epo isu ti a fi gun
iyan je, ki enia bo si ori atan ki o ma wa epo buredi, ki
elewa je ewa tan ki a ma fi nkan ha redi ikoko ewa, ki o
di pe Oloye n wa onke a ti itori be lo le gongo sile
olonje, ki okunrin ni woro ibante kan gege bi aso, ki
obinrin ma ni ju yeri
Kini Olusoro nsapejuwe?
b. Durko oruko ilu Baba ati iya Adiitu Olodumare
c. So eredi ti awon ebi Adiitu Olodumare fi talaka to be
d. Se apejuwe eranko ti a n pe ni Ilakose?
e. Ki ni iyato ti o wa laarin igbin ati ilakose
2a. Ise wo ni awon ara ilu ilakose nse
b. Fi ami si ori awon oro wonyii:
i. Ilakose
ii. Gongosu
iii. Alainironu
iv. Bamubamu
v. Alaimero
vi. Obo Lagido
c. Tani o n kigbe bayii
E:- e:- e:- e- E- e- e- E jowo e gba mi o – o – o ! Gbogbo
ara aiye, egba mi, gbogbo ero orun, egba mi, gbogbo
anjonnu aiye, egba mi, gbogbo sigidi adahunse, e gba
mi, sango, jowo gba mi, Jesu onigbagbo, Obatala jowo
gbami, Anabi onimale, gba mi, Edumare, temi dowo re,
gbogbo omo ilakose, agbe ilakose, onisowo ilakose, eni
keni ni ilakose, e jowo e gba mio:-:-:-:-:-:-o”
ADIITU OLODUMARE DI ERO INU IGBO
1a. Baba mi, mo dupe lopolopo fun bibi ti e bi mi. Lai se
ainiaini, bi o ba je bayi ni e wa tele, e ko ba ti ni ero pe
ki e bi mi, e ko ba tile le to eniti nni obinrin. Sugbon
ayipada ti de. O di owuro ana ti mo ti fie nu mi ba onje
mo, sugbon nko ri ki enyin papa jeun, nko siri ki Iya mi
bu okele. Nitorina, mo fe lati jade kuro ni arin ilu, ki n fi
ori le ibikibi ti mo ba ri, boya bi emi ba lo, enyin ati iya
mi le ri ona ati ma toju ara yin, a je pe ng o ri yin,
sugbon bi eleda ba pe oni ni arimo, a o ma pade ni ode
orun.
Tani o soro yii
Tani oro naa n bawi
Kini esi ti eniti o n baa wi fo
b. Ko lessee ohun ti o sele si Adiitu Olodumare ni ojo
meta lehin ti o gbera kuro nile
c. Bawo ni Adiitu Olodumare se pa ejo buburu naa
d. Odun meelo ni Adiitu Olodumare gbe ninu Igbo
e. Kini iyato ti o wa laarin eniyan ati obo
2a. Ha! Eleda mi, temi ti je?
Olodumare, temi ti je?
Temi ti je laarin omo enia?
Baba mi wa onje, ko ri je
Iya mi wa onje ko ri je
Mo t’ori bo ‘gbo nitori ati je
Mo di egbe akata tori ati je
Alabagbe kiniun, tori ati je
Ekeji Imado tori ati je
Ona kona tin g o ba gba loni,
Iwo eleda mi, ma sai ko mi
i. Nje a le pea won oro oke yii lewi bi
ii. Tani o so oro yii
iii. Kini o sele ti o fi so awon oro wonyii.
b. Fi ami si ori awon oro wonyii
i. Teletele
ii. Sobolo
iii. Bamubamu
iv. Apoluku
v. Jowolo
vi. Ajedubule
vii. Edegbewa
viii. Akosile
ix. Obiri Aiye
x. Adiitu
c. Kini oruko omo itunu-aye aiyedemi
d. Awon nkan Ogun wo ni won pin kan lehin iku baba re
e. Awon nkan Ogun wo ni won pin kan Ireke Onibudo
funra ara re
2a. Se apejuwe iyato ti o wa laarin awon aso wonyii –
etu, alari, adire, aso elepa, sanyan, aso oke, damaasi,
aran.
b. Daruko awon nkan ti Adiitu Olodumare ra lo fun Iya
re
c. Iru iku wo ni o pa awon obi Adiitu Olodumare
d. Awon ohun wo ni Adiitu Olodumare se ni iranti awon
obi re
e. Awon ise ilu wo ni o tun se pelu.
ADIITU OLODUMARE LA ALA IYANU
1a. Ni soki se akosile ohun ti Adiitu Olodumare ri ni oju
orun
b. Ki ni ise angeli itoju emi?
c. Kini awon eran ohun osin ti won n wo tele ara won fe
lo se
d. Daruko awon eranko osin ohun
e. Ise wo ni digi n se ninu ala naa
2a. Iru ile wo ni ile Ope je
b. Iru awon eniyan wo lo n wo ibe
c. Salaye lekunrere itumo ati nkan ti awon wonyii duro
fun
i. Ako-okuta orun
ii. Akuko Orun
iii.Ogunlogo Apoti
d. Se apejuwe bi Akuko orun se ri
e. Ni soki, so ohun ti o sele laarin Adiitu Olodumare ati
Obiri-aiye
ADIITU NFE IYUNADE
1a. Bawo ni Ademe to se je si Adiity Olodumare
b. Kini a n pe ni Iyun ni ile Yoruba
c. Ise wo lo n se
d. Bawo ni Iyunade se je si Ademeto
e. Tani oro yii n se apejuwe –
“O dara lomobinrin, egan lo ku. O pupa roboto, gbogbo
ara ri minijo, ko sanra bakiti lasan, beni ko ru han-gogo,
o ri sosoro o sig a die, gbogbo nkan ti obinrin fi iwu ni ni
o ni gbogbo, eyinloju mole kedere, ko pupa rakorako bi
oju ejo. Bi enia ba wo ipenpeju re o dabi eni pe
Olodumare da tire se loto, ti o to nkan dudu tere sii, ete
ko fele rekoja, beni ko nipon pon-on-pon, ehin funfun bi
ojo ojo, ese ko ri tere bi ese oga, beni ko ri jakiti bi ti
ajanaku, ori ko ri gidigbi, kori palaba, kori gboro, eleda
se e ni iwon tunwonsi, o ba orun mu.
d. Kini esi leta akoko ti Iyunade kosi Adiitu
e. Daruko awon nkan ti Adiitu fi ranse si Iyunade
2a. Bi o ba fe fun mi ni nkan gege bi ore egbon mi, mo
gbo, bi o ba se mi ni alejo ti ko ni igberaga ninu, mo
gba, ki a wipe agolo atike kan pere lo ra wa fun mi, o ba
ri I bi o ti ma niyi to lowo mi, se ni mba gbe o soke ke-
nke.
Inu leta tani eyi ti je jade?
b. Kini o sele ti Iyunade fi n fi Adiitu Olodumare se yeye
c. Fi ami si ori awon oro yii
i. Gombu
ii. Yereku
iii. Ikoko
iv. Iyunade
v. Onibuore
vi. Onimale
d. Kini iyato ti o wa laarin omo buroka ati ipata omo
e. Kini o fa ti ara Iyunade ko fi ya
3a. Tani o so oro yii
Egbon mi, nko le be Adiitu rara, e jowo e je kin lo ola ti
Olodumare fun mi gegebi Obinrin. Lona kini Adiitu kii
se oko mi, ki itile se oko afesona rara, ki a wipe a fe ara
wa nijomiran ni mo le bee, sugbon eyi ni papa ko le bo
sii.
b. ki lo de ti Iyunade pe Adiitu ni Ogonju Orun
c. Tani esu-lehin ibeji
d. Kini o de ti esu lehin ibeji fe fi pa Adiitu
e. Tani esu lehin ibeji pa dipo Adiitu Olodumare
EHIN IGBEYAWO ADIITU OLODUMARE
1a. Tani Enudunjuyo
b. Tani o so oro yii
“Gbogbo eyin omo Ajedubule, mo ki yin, gbogbo alejo
Ajedubule, mo ki yin, mo ki onile, mo ki alejo, mo ki oso,
mo ki aje, mo ki babalawo, mo ki adahunse, mo ki olowo,
mo ki talaka, mo ki eniti o rije, mo ki eyiti ko rije ,
gbogbo enyin igbagbo, mo ki yin, gbogbo enyin imale,
mo ki yin, gbogbo enyin aborisa mo ki gbogbo yin
porogodo.
c. Tani Oba Okonko
d. Kini Olori Esan-mbo se ti won fi ti mon inu iboji
e. Iru eniyan wo ni Alabapade je?
2a. Tani o gba ero lati pa Esan-mbo
b. Kini esi ti Esan mbo fun alabapade
c. Tani o n je omo owu
d. Ki ni alabapade ri lara esan-mbo nigba ti o fe sunmo
e. Tani o ko sibe
3a. Enu awon wo ni Oba ti gbo wipe Esan-mbo ko ku
b. Kini ase ti Oba Okonko pa fun awon onise re pe ki
won se fun Esa-mbo ati alabapade
c. Iru iya wo ni Oba Okonko fi je Esan-mbo
OJO KEJI NINU ILE MOGAJI ENUDUNJUYO
1a. Daruko awon eko ti a riko ninu itan Enudunjuyo
b. Iru eniyan wo ni Kotemilorun je
c. Ki ni oruko ore re
d. Iru awon Ibeere wo ni Esu Elegbara n bi awon ti won
wa si ipade
e. ki ni oruko ore Kotemilorun ti o bere lowo re wipe se
enia tun le lo si ibikan lehin iku?