e tthhaaammmeesss vviieeewww iiin nnfffaaanntttsss · 2018. 1. 9. · lati rí akoko lati sọrọ....

8
1 TVIacademy.org Thames View Infants: a company limited by guarantee Registered in England: Company Number: 08163191 Registered Office: Thames View Infants, Bastable Avenue, Barking, Essex IG11 0LG T T h h a a m m e e s s V V i i e e w w I I n n f f a a n n t t s s Ìwé Àlàyé Nípa Ilé-Ẹkọ Ìkíni kaabọ lati ọdọ gbogbo awọn Oṣiṣẹ ati Aláṣẹ sí Ile-Ẹkọ Agbàmì-ẹ̀yẹ, olóríṣi-àṣà tiwa. Mo gbagbọ wipe awọn ọmọde ní àǹfààní kan ṣoṣo lati ṣaṣeyọri ni Ìlé-ìwé atipe gbogbo agbara mi ni awọn ọdún mẹjọ sẹyin gẹgẹbi Olùkọ́-Àgbà ní TVI ni mo fi jìn fún ṣíṣe eyii lọna to dára: fífún awọn ọmọde wa – ati awọn idile wọn ní – ibẹrẹ igbesi-ayé todara jùlọ ati ikẹkọọ Awọn Èwe todara ati eyito ṣeé ṣe jùlọ. A ti ṣaṣeyọri t’oṣoro lati gbagbọ ninu eleyii: Ibití a dé ní Thames View Infants wa laarin awọn ilé-ìwé ìdá kan ninu márùn-ún towa loke gbogbo awọn ilé-ìwé jakejado orilẹ-ede yii atipe fun awọn ọdún kan bayii, a ti kà wá bíi Ilé-ìwé Àwọn Èwe to ńṣaṣeyọri jùlọ ninu Barking ati Dagenham, to sì ńta ọpọ ninu Àwọn Ilé-ìwé yọ kaakiri Lọńdọnu. DfE náà ti fi ipo àṣẹ wọn fún wa lámì gẹgẹbii Asiwaju Jakejado Orilẹ-ede ninu Ẹkọ ati Ilé-ìwé Àkànṣe Iṣatilẹyinfunni. Àwa ni Ofsted dáláre gẹgẹbii “Alatawọnyọ” lẹẹmeji (ni 2009 ati lẹẹkansi, ni 2014). A nigbagbọ wipe a ó máa tẹsiwaju ninu awokọṣe daradara yii. Àwọn oṣiṣẹ mi ati Èmi ni a ti farawajin fun mimu ohun todara jade fun ìwọ ati idile rẹ. Jọwọ fi ọkàn balẹ nitoripe a ó gbiyanju gidigidi lati fun ọmọ rẹ ni ìrírí ikẹkọọ to ṣeé ṣe jùlọ tí a ó sì fún ọ ní iṣẹ oníìbárà aláàpẹrẹ ati atilẹyin idile. Ninu àpò-ìwé ni a fi awọn alaye pataki tosi wúlò ni ṣókí sí fún ọ. Pẹlu atilẹyin ati jijẹ òbí tó ńkíyèṣára oníyelóri rẹ, ọmọ rẹ yóò fi Ilé-ìwé wa silẹ pẹlu igbaradi totayọ fun Ipele tókàn ninu Ẹkọ wọn: Àwọn Ọmọ Orilẹ-ede Biriteeni ńlá – tíatiró lágbára, onigboya, awọn asiwaju ọjọ ọla, ẹlẹyinju-aanu, alálàyé & olóye, onípamọra ati awọn ọga ninu Mimọ-ọn-kọ ati Mimọ-ọn-ka ati Kíka Òǹkà. Paul Jordan, Olùkọ́-Àgbà. Àṣà Ihuwasi Wa Ní Thames View Infants a ń ṣiṣẹ kárakára lati pese ilé- ìwé awujọ, onitọju, amuni- ẹnidun ati aṣatilẹyin kan, ninu eyiti gbogbo ọmọ ati idile wọn, tiṣe pataki gidi. A ńpese ayika ikẹkọọ kan, nibiti ẹnikọọkan, ti ńdé ẹkunrẹrẹ ipá towaninu wọn, laifi ibi ti wọn ti bẹrẹ ṣe A ń kọ awọn ọmọde lati máa bọwọ, tẹwọgbà atipe ki wọn ka awọn ọmọ kilaasi ati awọn agba sí ninu ilé-ìwé àwùjọ, olóríṣi-àṣà wa ati ninu igbesi aye wọn lẹyin ilé-ìwé nipa jijẹ awọn awokọṣe rere. YORUBA

Upload: others

Post on 06-Mar-2021

0 views

Category:

Documents


0 download

TRANSCRIPT

Page 1: e TThhaaammmeesss VViieeewww IIIn nnfffaaanntttsss · 2018. 1. 9. · lati rí akoko lati sọrọ. Bí ìwọ, tabi ọmọ rẹ bani ibeere nipa iṣẹ amurele tabi nilo imọran

1 TVIacademy.org

Thames View Infants: a company limited by guarantee Registered in England: Company Number: 08163191 Registered Office: Thames View Infants, Bastable Avenue, Barking, Essex IG11 0LG

TTThhhaaammmeeesss VVViiieeewww IIInnnfffaaannntttsss

Ìwé Àlàyé Nípa Ilé-Ẹkọ

Ìkíni kaabọ lati ọdọ gbogbo awọn Oṣiṣẹ ati Aláṣẹ sí Ile-Ẹkọ Agbàmì-ẹ̀yẹ, olóríṣi-àṣà tiwa. Mo gbagbọ wipe awọn ọmọde ní àǹfààní kan ṣoṣo lati ṣaṣeyọri ni Ìlé-ìwé atipe gbogbo agbara mi ni awọn ọdún mẹjọ sẹyin gẹgẹbi Olùkọ́-Àgbà ní TVI ni mo fi jìn fún ṣíṣe eyii lọna to dára: fífún awọn ọmọde wa – ati awọn idile wọn ní – ibẹrẹ igbesi-ayé todara jùlọ ati ikẹkọọ Awọn Èwe todara ati eyito ṣeé ṣe jùlọ. A ti ṣaṣeyọri t’oṣoro lati gbagbọ ninu eleyii: Ibití a dé ní Thames View Infants wa laarin awọn ilé-ìwé ìdá kan ninu márùn-ún towa loke gbogbo awọn ilé-ìwé jakejado orilẹ-ede yii atipe fun awọn ọdún kan bayii, a ti kà wá bíi Ilé-ìwé Àwọn Èwe to ńṣaṣeyọri jùlọ ninu Barking ati Dagenham, to sì ńta ọpọ ninu Àwọn Ilé-ìwé yọ kaakiri Lọńdọnu. DfE náà ti fi ipo àṣẹ wọn fún wa lámì gẹgẹbii Asiwaju Jakejado Orilẹ-ede ninu Ẹkọ ati Ilé-ìwé Àkànṣe Iṣatilẹyinfunni. Àwa ni Ofsted dáláre gẹgẹbii “Alatawọnyọ” lẹẹmeji (ni 2009 ati lẹẹkansi, ni 2014). A nigbagbọ wipe a ó máa tẹsiwaju ninu awokọṣe daradara yii. Àwọn oṣiṣẹ mi ati Èmi ni a ti farawajin fun mimu ohun todara jade fun ìwọ ati idile rẹ. Jọwọ fi ọkàn balẹ nitoripe a ó gbiyanju gidigidi lati fun ọmọ rẹ ni ìrírí ikẹkọọ to ṣeé ṣe jùlọ tí a ó sì fún ọ ní iṣẹ oníìbárà aláàpẹrẹ ati atilẹyin idile. Ninu àpò-ìwé ni a fi awọn alaye pataki tosi wúlò ni ṣókí sí fún ọ. Pẹlu atilẹyin ati jijẹ òbí tó ńkíyèṣára oníyelóri rẹ, ọmọ rẹ yóò fi Ilé-ìwé wa silẹ pẹlu igbaradi totayọ fun Ipele tókàn ninu Ẹkọ wọn: Àwọn Ọmọ Orilẹ-ede Biriteeni ńlá – tíatiró lágbára, onigboya, awọn asiwaju ọjọ ọla, ẹlẹyinju-aanu, alálàyé & olóye, onípamọra ati awọn ọga ninu Mimọ-ọn-kọ ati Mimọ-ọn-ka ati Kíka Òǹkà. Paul Jordan, Olùkọ́-Àgbà.

Àṣà Ihuwasi Wa

Ní Thames View Infants a ń ṣiṣẹ kárakára lati pese ilé- ìwé awujọ, onitọju, amuni-ẹnidun ati aṣatilẹyin kan, ninu eyiti gbogbo ọmọ ati idile wọn, tiṣe pataki gidi.

A ńpese ayika ikẹkọọ kan, nibiti ẹnikọọkan, ti ńdé ẹkunrẹrẹ ipá towaninu wọn, laifi ibi ti wọn ti bẹrẹ ṣe

A ń kọ awọn ọmọde lati máa bọwọ, tẹwọgbà atipe ki wọn ka awọn ọmọ kilaasi ati awọn agba sí ninu ilé-ìwé àwùjọ, olóríṣi-àṣà wa ati ninu igbesi aye wọn lẹyin ilé-ìwé nipa jijẹ awọn awokọṣe rere.

YORUBA

Page 2: e TThhaaammmeesss VViieeewww IIIn nnfffaaanntttsss · 2018. 1. 9. · lati rí akoko lati sọrọ. Bí ìwọ, tabi ọmọ rẹ bani ibeere nipa iṣẹ amurele tabi nilo imọran

2 TVIacademy.org

Thames View Infants: a company limited by guarantee Registered in England: Company Number: 08163191 Registered Office: Thames View Infants, Bastable Avenue, Barking, Essex IG11 0LG

A fẹ ki awọn ọmọde gbadun akoko wọn ni ilé-ìwé atipe a ti ṣẹda ayika alailewu tórọrùn kan nibiti wọn yóò ti mọ wipe a ńtọju wọn, tí a sì kawọn sí, nipa mimu ominira, igboya ati ipá awọn ọmọde láti ṣe ìpinnu funra wọn dàgbà.

A ńlépa lati jẹki àwùjọ ilé-ìwé wa máa kínni kaabọ kosi fanimọra atipe a lero wipe awọn òbí ati olukọ ńṣiṣẹ papọ lọna kan náà lati ṣeranwọ ati atilẹyin fun awọn ọmọde náà.

Gẹgẹbi a tifẹ lati ran àwọn idile lọwọ lati gba eyito dara julọ lati inu àkókò wọn pẹlu wa, a ńṣe ọpọlọpọ iṣẹ eyiti o ńmú ohun ti ilé-ìwé leè ṣe funni gbòòrò ati ọjọ ilé-ìwé.

Bákannáà, a ń ṣiṣẹ papọ pẹlu gbogbo awọn akọṣẹmọṣẹ ẹlẹgbẹ wa toṣe pataki laarin adugbo tí a sì ńfi ara wa yangàn lori awọn iṣopọ rere wa. Ninu wọn ni Thames View Junior School, Ibudo Awọn Ọmọde ti Sue Bramley, Ile-iwe Jeleosinmin Chestnuts, Ile-Iwosan Thames View, Ile-iwe Jeleosinmi Sparrows (ti a mọsi Christchurch tẹlẹ), Awọn Iṣe Igbaye-gbadun, awọn ile-iwe towa nitosi ati awọn iṣẹ eto ẹkọ ati iṣatilẹyin laarin Ẹka Isakoso Lọndọnu ti Barking ati Dagenham.

Lapapọ a ńfun awọn idile latilẹyin alaṣopọ kan ati ipese ẹkunrẹrẹ ti a “so papọ” kan.

Àwọn Àkókò Ilé-ìwé

Jeleosinmi Ọdún 3-4 8:45ow sí 11:45ow ati 12:30ọs to 3:30ọs

Igbanilalejo Ọdún 4-5 8:55ow sí 11:45ow ati 1:00ọs to 3:15ọs

Ọdún 1 & Ọdún 2

Ọdún 5-6 Ọdún 6-7

8:55ow sí 12:15ọs and 1:15ọs to 3:15ọs

Jọwọ gbiyanju lati rii daju wipe ọmọ rẹ dé lasiko. Kilaasi kọọkan ńbẹrẹ ọjọ pẹlu iṣẹ imọọn-kọ-mọọnka ati kika òǹkà atipe ọmọ rẹ yóò máa pàdánù ikẹkọọ pataki bí wọn bápẹ.

Lépa lati dé ni bii iṣẹju saaju ki ilé-ìwé to bẹrẹ, nitoripe o koni fẹ lati duro pẹ ju botiyẹ lọ, papaa ni awọn ọjọ òtútù.

Page 3: e TThhaaammmeesss VViieeewww IIIn nnfffaaanntttsss · 2018. 1. 9. · lati rí akoko lati sọrọ. Bí ìwọ, tabi ọmọ rẹ bani ibeere nipa iṣẹ amurele tabi nilo imọran

3 TVIacademy.org

Thames View Infants: a company limited by guarantee Registered in England: Company Number: 08163191 Registered Office: Thames View Infants, Bastable Avenue, Barking, Essex IG11 0LG

A ńṣe Ẹgbẹ Oúnjẹ Owurọ kan fun awọn òbí ti awọn ọmọ ninu KS1 tó ńṣiṣẹ, eyiti ó ńbẹrẹ lati 8:00ow, pẹlu igbaniwọle ni 8:20. Awọn ọmọde ni awọn oṣiṣẹ ilé-ìwé ńbojuto. Owó kekere kan wa lati san. Gbogbo awọn ọmọde kọni ìbẹrẹ toya rọ lọrun atipe bí o bafẹ kí ọmọ rẹ wá sí Ẹgbẹ Oúnjẹ Owurọ, jọwọ wa lati bá Claire Smith, Igbakeji mi sọrọ.

Bi o bapẹ, jọwọ máṣefi ọmọ sílẹ sile fun ọjọ náà – ó tẹwalọrun kí ọmọ pẹẹ de ju

ki o ṣe alaiwa rara lọ. Nigbati o bade ilé-ìwé o nilo lati rí oṣiṣẹ ọfiisi náà lati ríi daju wipe a forukọ ọmọ rẹ silẹ wipe ó wá ki a sì pàṣẹ fun oúnjẹ kan.

Àwọn Àfojú-inúSe Ilé-iwé

Gẹgẹbii ‘ilé-ìwé alaamugbooro’ kan, a ńpese oriṣiriṣi awọn iṣẹ ẹlẹgbẹẹgbẹ nirọlẹ fun awọn ọmọde, eyiti awọn ọmọde leè wá lọfẹẹ. Ninu wọn ni idanilẹkọọ lori bọọlu alaafẹsẹgba, ijo jijo ati lilo ẹrọ kọmputa. Lẹẹkan sii, gbogbo awọn ọmọde kọni ọjọ ti a mugbooro kan rọ lọrun ṣugbọn a máa ńgbiyanju lati faaye gba ifẹ ẹnikọọkan nigbati a bá ńfi awọn ẹgbẹ bá awọn ifẹ ọkan onikaluku dọgba.

A tún ní Oludamọran Isatilẹyin-Òbí kan, ẹniti o ńṣètò oriṣiriṣi ẹgbẹ fawọn òbí, tosi lee ṣeranwọ nipa pupọ ninu awọn iṣoro tí awọn idile ńdojukọ lojoojumọ. Wọle wa lati pin awọn idaamu eyikeyii ti o lee ni ki wọn ó tó di titobi jù botiyẹ.

Gbogbo awọn ọmọde ni Ọdún 2 niwọn leè yá ẹrọ ọpọn-imọ iPaadi kan tabi kopa ninu Eto Ràá-padà tikiiṣé dandan kan. A jẹ ilé-ìwé kan “Tolọrọninu-Imọ Kọmputa” atipe a tigba ọpọ awọn àmì ẹyẹ lorilẹ-ede yii fun ipese tojinlẹ yii. Awọn ọmọde ni gbogbo ilé-ìwé náà nlo awọn ẹrọ alaagbeletan, iPaadi, Andirọidi, awọn Wiis/Xbox ati awọn imọ-ẹrọ igbalode mii.

Aláàkóṣo Imọ-ẹrọ wa yóò dahun awọn ibeere eyikeyii tí o bani pẹlu Kọmputa ilé rẹ. Wá láti bá a sọrọ atipe yóò ṣe eyito dara julọ lati ṣatilẹyin fun ọ ati lati pese iranwọ toṣeé mulo.

A mọ rírì “Àwọn Òbí bíi Aláàbáṣiṣẹpọ” atipe ìkànsíraẹni todara laarin ilé ati ilé-ìwé ṣe pataki. Àwọn ọna pupọ lowa lati jẹki o máa kàn síwa tabi ki o máa beere ohun tó ńlọ lẹyin awọn ìtàgé náà: Ohun akọkọ lati ṣe nilati gba Ohun-èlò wa sọkalẹ. Yóò gbà ọ láàyè lati: fi awọn èrò ọkàn rẹ hàn síwa ka awọn bulọọgi akọjade wa ṣayẹwo awọn déètì ati iṣẹlẹ ṣabẹwo-sáàyè ayélujára ilé-ìwé kàn síwa lẹyin awọn wakati ikẹkọọ forukọ silẹ fun atokọ fifi lẹta-onidijita ranṣẹ wa

(atipe o kosi ni padanu lẹta pataki kankan mọ!)

Page 4: e TThhaaammmeesss VViieeewww IIIn nnfffaaanntttsss · 2018. 1. 9. · lati rí akoko lati sọrọ. Bí ìwọ, tabi ọmọ rẹ bani ibeere nipa iṣẹ amurele tabi nilo imọran

4 TVIacademy.org

Thames View Infants: a company limited by guarantee Registered in England: Company Number: 08163191 Registered Office: Thames View Infants, Bastable Avenue, Barking, Essex IG11 0LG

Awọn oṣiṣẹ Mi ati Èmi máa ń Tweet lojoojumọ: ohun ni ọna tóyá tosi dara jùlọ lati beere nipa ohun to ńlọ layika Ilé-ìwé. Ṣe alaabapin sí awọn ìkósínú Twitter wa ki o si mọ pupọ diẹ síi:

@TVInfants (Paul Jordan, Olukọ-àgbà) @ClaireTVInfants (Claire Smith, Igbakeji Olukọ-àgbà)

@Khaled_a_Ali (Khaled Ali, Olórí ti EYFS) @TVI_MissCJones (Rosa Corcoran-Jones, Amugbalẹẹgbẹ Olukọ-àgbà) @FiBashirTVI (Fi Bashir, Akọṣẹmọṣẹ nipa Ọmọde ati Idile) @TVI_ICTSupport (Simon Mordecai, Alaakoṣo Imọ-ẹrọ Kọmputa)

Máa foju sọna lori Ìkànnì “YouTube”… Thames View Infants TV (TVI TV). O ní awọn fidio tó léní 250 ti agbejade Pọdikasiti Àwọn Olukọ ati awọn Ìsínilétí Towaloke fún ikẹkọọ!

O dara jùlọ lati pade pẹlu awọn olukọ wa ‘lónífojú-kojú’, papaa nigbati o ba ńsọrọ nipa ikẹkọọ. Botiwukori, ó yéwa wipe igbesi aye awọn òbí leè jẹ eyiti kodilẹ rárá nitori iṣẹ atipe nigbamiran ó ṣòro lati rí akoko lati sọrọ. Bí ìwọ, tabi ọmọ rẹ bani ibeere nipa iṣẹ amurele tabi nilo imọran lori iwe kika nile, o leè fi ì-meèlì ranṣẹ sí:

[email protected]

Awọn olukọ wa yóò gbiyanju lati dahun ibeere rẹ, tabi fun ọ ladehun ipade lati ràn ọ lọwọ siwaju síi ni akoko to rọrùn kan.

Asọ Ilè-ìwé jẹ dandan ni Ilé-Ẹkọ wa. Wíwọ asọ ilé-ìwé ńṣe iranwọ lati ṣẹda ironu wipe mojẹ ara ilé-ìwé náà atipe ó ńfi ipa ọna silẹ fun agbègbè ibi iṣẹ rere kan. Àwọn ọmọde ńwọ asọ ṣẹẹti pólò, eyito wanilẹ ni ọfiisi ilé-ìwé ni ọkan ninu awọn awọ to ńtán 6 – funfun bíi òjò-dídì, olorombo, yẹlo bíi òòrùn, pọpu aládé, pipọn bíi ata ati tọkọisi alayọ. Àwọn ọmọde leè wọ awọ eyikeyii lọjokọjọ, ṣugbọn wọn gbọdọ wọ asọ ṣẹẹti pólò kan. A tọrọ afofijin, sugbọn a kò faaye gba awọn ọmọde lati wọ ọṣọ bíi yẹrí etí ní ilé-ìwé. O jẹ ohun tí ko dara fun ìIera awọn

ọmọde lati wá sí ilé-ìwé ninu asọ awọju ní akoko ooru. Àwọn ọmọde máa ńṣeré ní ilé-ìwé atipe wíwọ ọpọ asọ onípele ti a ko nilo (awọtẹlẹ, lẹgiisi, ṣẹẹti ati jọmpa) yoo fa ooru àmújù fun ọmọde. Yoo tun faaye silẹ fawọn nǹkan lati ṣọnù bí wọn bati ńbọ awọn ipele asọ lati gba atẹgun. Jọwọ wọ asọ toba igba mu fun ọmọ rẹ. Nitiwa, a o ṣeranwọ fun wọn lati wa ni ilera (pẹlu rírówọn lagbara lati bọ asọ ati lati wọ wọn padà nigbati toba gbona tabi tutù jù).

W íwá Sí Ilé-ìwé

O jẹ dandan labẹ òfin pe ki awọn ọmọde máa wá sí ilé-ìwé déédéé, atipe awọn

òbí ati olutọju gbọdọ ríi daju wipe eyii ńṣẹlẹ. Àìwá eyikeyii, yatọsi nitori àìlera, ni a ko faaye gbà.

Page 5: e TThhaaammmeesss VViieeewww IIIn nnfffaaanntttsss · 2018. 1. 9. · lati rí akoko lati sọrọ. Bí ìwọ, tabi ọmọ rẹ bani ibeere nipa iṣẹ amurele tabi nilo imọran

5 TVIacademy.org

Thames View Infants: a company limited by guarantee Registered in England: Company Number: 08163191 Registered Office: Thames View Infants, Bastable Avenue, Barking, Essex IG11 0LG

Gbogbo awọn ọjọ isinmi idile ni a gbọdọ gbà nigba isinmi ilé-ìwé ti a ṣagbejade wọn. Ilé-ìwé koni fun idile eyikeyii ni awọn ààyè isinmi laarin akoko ẹkọ. Àwọn òbí toba lọ láìlàgbàṣẹ tabi tayọ awọn déètì atipadade ni yóò wa ninu ewu:

Akiyesi Ìjẹniníyà Alaiyipada kan (owó ìtanràn) fun àgbà ATI fun ọmọ kan (kódà bí awọn ọmọ miran bá ńlọ si ilé-ìwé kan toyatọ).

Pipadanu ààyè ọmọ ni ilé-ìwé náà.

Ṣíṣe-atunforukọsilẹ pẹlu Ijọba Ibilẹ fun ààyè ilé-ìwé tuntun kan. Àlàyé nipa idile á di fífiranṣẹ sí Oṣiṣẹ Iwasile-iwe ti Ẹka Isakoso náà.

Ṣugbọn, bí ọmọ koba fẹ lati máa wá si ilé-ìwé lẹyin náà bá wa sọrọ. O leè ní ìdí kan fun eyii atipe a ó dìjọ ṣiṣẹ papọ lati yanju ìṣòro náà.

Wíwá déédéé ati dídé láàkókò rere ṣe pataki bí àwọn ọmọde yóò bá ṣaṣeyọri ní ilé-ìwé.

Kínni monilati se bí ara ọmọ mi kòbá yá?

Bí ọmọ rẹ bá ńṣe aisan gidigidi nigba náà jẹki wọn duro nílé tí ara wọn yóò fi yá ninu ibusun.

Bí eyii bajẹ iṣẹlẹ náà, a fẹ kí o pe (020 8270 4317) tabi tẹ akọranṣẹ sí (07943 922 655) ọfiisi ilé-ìwé wa kí ó tó di aago 10ow lojoojumọ ọjọ tíwọn fiṣe aláìwà kí ó sì sọ bíwọn ti ńṣe fun wa. A ńtẹle imọran lori ailera atipe a ó fun ọ lamọran bakan náà.

A ńfúnni ni ayika tó ńtọju tosi tun ńṣatilẹyin ẹni, atipe a leè ran ọmọ rẹ lọwọ lati pada si ilé-ìwé ni kiakia ni ọpọlọpọ ọna:

Fifun ọmọ rẹ ni awọn oogun (bí o bá fọwọsí fọọmu akanṣe kan lati ọfiisi náà)

Fífi 'ojú miran' bojuto ọmọ rẹ nigbati ara wọn bá ńmókun lọwọ ati kí a máa jẹki o mọ nipa 'bí wọn báti ńṣe'.

Bíbá awọn oniṣegun GP sọrọ ni Ile Iwosan Thames towa laadugbo wa.

Pipese awọn ẹyan ounjẹ miran fun wọn ni ọsan (nipa ètò akanṣe).

Ṣíṣiṣẹ papọ pẹlu iwọ ati ọmọ rẹ bi ara wọn koba tètè balẹ tabi o bá ńní ìṣòro lati múwọn wa si ilé-ìwé lowurọ ọjọ kọọkan.

Ṣíṣe ìrànwọ kiwọn leè mọ iṣẹ tiwọn ti padanu.

Page 6: e TThhaaammmeesss VViieeewww IIIn nnfffaaanntttsss · 2018. 1. 9. · lati rí akoko lati sọrọ. Bí ìwọ, tabi ọmọ rẹ bani ibeere nipa iṣẹ amurele tabi nilo imọran

6 TVIacademy.org

Thames View Infants: a company limited by guarantee Registered in England: Company Number: 08163191 Registered Office: Thames View Infants, Bastable Avenue, Barking, Essex IG11 0LG

Kínni "wíwásílé-ìwé todara"? Nitoripe o leè ṣe àkóbá fun ẹkọ ọmọde bíwọn koba wá sí ilé-ìwé déédéé, ijọba tiṣe ètò Afojusun Jakejado Orilẹ-ede fun Wíwásílé-ìwé tí gbogbo ilé-ìwé nilati lépa, tojẹ wipe awọn ọmọ ilé-ìwé gbọdọ wá nigba ìdá 95 ninu 100 fun gbogbo ṣáà ikẹkọọ.

Eyii tumọsi wipe, ninu ọdún kan, awọn ọmọde padanu ọjọ ikẹkọọ 1 péré lóṣù kan (tabi ilaji-ọjọ laarin ọṣẹ meji). A jẹ oloriire, nitoripe awọn ọmọde kìí sáábà ṣe aláìwá ní ilé-ìwé wa.

Lọwọlọwọ ní Thames View Infants ọpọ awọn ọmọde ńwá lojoojumọ tíwọn sì ńní ìdá 100 ninu 100.

Ni gbogbo ṣáà ikẹkọọ a ńfún gbogbo idile toba gba àmì ìdá 100 ninu Wíwásílé-ìwé ni akanṣe "Ipejọpọ Òdòdó" to gbajumọ kan.

A tún ńfún ọmọ kan toba fi ilọsiwaju tóyanranntí hàn ninu wíwásílé-ìwé rẹ laarin ọdún kan sí déètì náà lẹbun kẹkẹ kan.

Báwo ni Mo se leè mọ bí wíwásílé-ìwé ọmọ mi tise rí? A ńṣiṣẹ alajumọṣe pẹlu awọn idile ati, bíi ilé-ìwé kan, a ńbojuto wíwásílé-ìwé laidawọduro. Ní ọpọ igba, iwọ yóò ti mọ tẹlẹ bí wíwásílé-ìwé ọmọ rẹ báti jálọ silẹ nitoripe ní ọgangan ibi kan, a ó ti jọ sọrọ papọ nipa rẹ. Lati igba de igba, ni gbogbo ọṣẹ meji, a máa ńṣayẹwo ìwásílé-ìwé gbogbo awọn ọmọde wa. Ní ṣáà ẹkọ kọọkan, a máa ńkọ lẹta sí òbí kọọkan bí ìwásílé-ìwé ọmọ wọn ba jálọ silẹ kọja awọn ipele tobanilẹru nisalẹ wọnyi:

100% (kòṣe aláìwá nigba kankan) 97% (bíi aláìwá ilaji-ọjọ-kan loṣu kan) Under 95% (aláìwá ilaji-ọjọ kan lọṣẹ meji) Under 90% (ilaji-ọjọ-kan lọṣẹ kan) Under 85% (ó fẹrẹ tó ọjọ kan lọṣẹ kan) Under 75% (ó fẹrẹ tó ọjọ-kan-ati-aabọ lọṣẹ kan)

Botilẹjẹpe wíwá fun ìdá 90 ninu 100 ti àkókò dabi eyito ga, lori iṣẹ ètò ẹkọ ọmọ kan, ìdá 10 tí a padanu leè jásí pipadanu odidi ọdún ikẹkọọ kan. Nipa pipe akiyesi rẹ síi nipaṣẹ lẹta, a leè dìjọ ṣiṣẹ papọ lati mu ilọsiwaju bá wíwásílé-ìwé ọmọ rẹ ati aṣeyọri rẹ bíi akẹkọọ kan.

Page 7: e TThhaaammmeesss VViieeewww IIIn nnfffaaanntttsss · 2018. 1. 9. · lati rí akoko lati sọrọ. Bí ìwọ, tabi ọmọ rẹ bani ibeere nipa iṣẹ amurele tabi nilo imọran

7 TVIacademy.org

Thames View Infants: a company limited by guarantee Registered in England: Company Number: 08163191 Registered Office: Thames View Infants, Bastable Avenue, Barking, Essex IG11 0LG

Kínni àwọn ipa osunwọn wíwásílé-ìwé tólọ silẹ?

Ṣiṣe aláìwásílé-ìwé déédéé leè kóbá ẹkọ ọmọ kan gidigidi. Nipa iṣiro iṣatupalẹ, awọn ọmọde tiwọn ní wíwásílé-ìwé ìdá 90 ninu 100 ló máa ngba máàkì to dara ju ninu idanwo atipe awọn ló ṣeé ṣe fun lati rí iṣẹ lọjọ ọla wọn.

Awọn ọmọde ti wíwásílé-ìwé wọn burú jáì máa ńní ìṣòro lati ni ironu wipe awọn jẹ ara igbesi ayé ilé-ìwé atipe wọn ńfẹ máa ní ìyọnu lati ba eniyan ṣọrẹ.

Awọn ọmọde máa ńrí wipe ó le diẹ síi fun awọn lati ‘ṣe àlébá’ awọn iṣẹ tíwọn ti padanu bí wọn kòbá wásí ilé-ìwé déédéé

Lọpọ igba, awọn ọmọde ti kìí sí ní ilé-ìwé déédéé ni wọn máa ńsáábà wà larọwọto iṣẹlẹ buruku.

Ilé-ẹkọ yii nṣiṣẹ papọ pẹlu Ẹka Isakoso Ijọba Ibilẹ ti Barking ati Dagenham, ti yóò pe awọn idile toba kuna lati ríi daju wipe ọmọ wọn ńwá sílé-ìwé déédéé lẹjọ, nitoripe o jẹ ohun tolodi sofin. Awọn Òbí/Olutọju ńfi ewu sisan owo itanran ṣeré, taki ki a gbewọn lọ sile ẹjọ, mimu wọn wasi kilaasi jijẹ òbí tabi fífi wọn sẹwọn ninu awọn ẹjọ toba burú jùlọ. A kofẹ ki eyii ṣẹlẹ sí idile ọmọ akẹkọọ Thames View Infants eyikeyii.

Ilé-ìwé wa jẹ ayika tó ńtọju ẹni tósì tún layọ kan, ati pẹlu atokọ orukọ gíga ti awọn to nduro kan, kosi dara bẹẹ fun awọn idile yẹn tiwọn fi ọmọ si ilé-ìwé wa, ṣugbọn kòṣeé ṣe nitoripe ó ti kún.

Awọn Ètò Ìgbaniwọlé

A ní iye nọmba àwọn ààyè tí kòṣeé yipada ninu ẹgbẹ ọdún kọọkan. Thames View Infants ńtẹle awọn ètò ìgbaniwọlé ti a fọwọsi lati Ẹka Isakoso ti Barking ati Dagenham. Bi koba si awọn ibeere diẹ síi mọ fun awọn ààyè ni ilé-ìwé ju iye nọmba ti a leè gbàwọlé, lẹyin náà Ijọba Ibilẹ leè gba gbogbo awọn ọmọde tonilo awọn ààyè wọlé. Bi awọn tofẹ lati wọle bá pọju awọn ààyè lọ, lẹyin náà Ijọba Ibilẹ nilo lati ní awọn àmúyẹ fun ìgbaniwọlé lati pinnu ẹniti yóò rí tabi tí koni rí ààyè kan. Awọn àmúyẹ fun ìgbaniwọlé náà ní àwọn àtẹlé yii:

Page 8: e TThhaaammmeesss VViieeewww IIIn nnfffaaanntttsss · 2018. 1. 9. · lati rí akoko lati sọrọ. Bí ìwọ, tabi ọmọ rẹ bani ibeere nipa iṣẹ amurele tabi nilo imọran

8 TVIacademy.org

Thames View Infants: a company limited by guarantee Registered in England: Company Number: 08163191 Registered Office: Thames View Infants, Bastable Avenue, Barking, Essex IG11 0LG

1. "Awọn Ọmọde Ti A Ńbojuto". 2. Awọn ọmọde ti wọn ni arakunrin tabi arabirin to ńwásí ilé-ìwé náà tabi Thames View

Junior School. 3. Awọn ọmọde to ńgbé nibito sunmọ ilé-ìwé julọ nipa odiwọn ọna afẹsẹrin náà tówà nitosi

julọ.

Awọn ọmọde ti a koba funni ààyè kan ni a ó forukọ wọn sori atokọ awọn to nduro fun ààyè to ṣófo kan.

Awọn Ìlànà fún Ifẹjọsun

A ńgbiyanju lati pese ẹkọ todara fun gbogbo awọn ọmọde wa. Olukọ-Agba ati awọn oṣiṣẹ ńṣiṣẹ gidigidi lati ṣagbekalẹ ibaṣepọ elérè pẹlu gbogbo awọn òbí. Botiwukori, Thames View Infants, bíi Ilé-ẹkọ, ni o gbọdọ ní nipaṣẹ òfin, ki o si ṣagbejade fun awọn òbí ìlànà wọn fun ifẹjọsun. Lati igba de igba awọn òbí ati olutọju yóò ní awọn ohun tómuwọn lọkan tositun bofinmu nipa ilọsiwaju, aṣeyọri, ihuwasi, tabi igbaye-gbadun ọmọ wọn, tabi nipa awọn ọrọ miran tó nííṣe pẹlu ilé-ìwé. Pupọ ninu awọn ede-aiyede ni a kìí mọ-an-mọ jẹ koṣẹlẹ atipe awọn olukọ wa yóò tẹti gbọ ọ tí wọn yóò sì ṣe ohun todara julọ lati yanju ọrọ náà. Ninu ọpọ iṣẹlẹ o dara ju lati pe akiyesi wa si ọrọ eyikeyii tabi ba olukọ ọmọ náà sọ ọ tààrà lati bẹrẹ; botiwukori, ni iduro lori bíi ifẹjọsun náà tiṣe rí, o leè di dandan fun ọ lati pe akiyesi Olukọ-agba si ọrọ náà tààrà – ẹniti, ni iduro lori bíi iṣẹlẹ náà tiṣe rí, yóò yanju ọrọ yálà nipati ọwọ ilé tabi nipati ilana òfin. Awọn ifẹjọsun ni a ńyanju nipa Igbesẹ Onípele-4, eyiti a leè wò ní kíkún níbí: http://is.gd/I9bK7f

Ìlànà Ìfẹnukò Ihuwasi & Dídáààbò-boni

A ńtẹle oriṣiriṣi Ìtọniṣọna lati leè máa peregedè ninu Awọn Ojúṣe wa lati ríi daju wipe awọn ọmọde wa wà labẹ ààbò atipe a ńfún wọn nitọju todara. Nigba miran, o di dandan fun wa lati pin awọn àlàyé pẹlu Iṣẹ Igbaye-gbadun tabi Oṣiṣe Ijọba Ibilẹ Tiafunlaṣẹ (fun Ààbò Ọmọde) ki a si gba imọran wọn tabi itọni wọn. Gbogbo wa tún ni ojuṣe ti itọju ati iṣe lati huwa botiyẹ ati bí akọṣẹmọṣẹ nigbati a bawa ninu Ọgbà Ilé-ìwé. Ṣíṣe bẹẹ, ńgbárùkùti ajọṣepọ iṣẹ tódán mọran kan, lati inu eyiti, awọn ọmọde ti leè dagba kiwọn situn ṣaṣeyọri. Ẹda ti Ìlànà Ìfẹnukò Ihuwasi kan ni a ṣafihan rẹ laarin Ọfiisi Ilé-ìwé wa. A nireti wipe awọn àlàyé yii ti wulo fun ọ. Botiwukori, ó kàn ńṣọ fun ọ nipa awọn nǹkan diẹ ti a ńṣe ni ilé-ìwé wa ní – nitori náà jọwọ wá lati beere nipa ohun miran tí o bafẹ lati mọ ní Ọfiisi Ilé-ìwé, bíi awọn owurọ kọfí wa, bí o ti leè jẹki a máa fi lẹta-onidijita wa ranṣẹ sí ọ … tabi kí o kàn ṣe ẹ pẹlẹ nibẹ un siwa! Ọpọ awọn àlàyé ati ohun amuṣọrọ mii lowa nilẹ ni ojú-òpó ayélujára ilé-ìwé wa:

TVIacademy.org