okowo gbaguda: ere jije ati ona ti a file din inawo...

2
Iṣẹ Akanṣe Alasopọ nipa Iwulo Iyẹfun Paki ti o dara jọjọ, jẹ eleyi ti Ajọ Isuna awon Orile-ede fun Idagbasoke Iṣẹ- ọgbin (IFAD) se atilẹyin rẹ, nigbati Ajọ tinse iwadi fun ise ogbin ni ile Adulawo si jẹ adari rẹ. Iṣẹ Akanṣe Alasopọ Iwulo Iyẹfun Paki, eyi ti o dara jọjọ, nii lọkan lati fidi mulẹ ni orilẹ-ede Naijiria. Ni ilakaka lati ri wipe ilepa re wa si imuṣẹ, ati lati sọ ilepa naa di nla, iṣẹ akanṣe naa ti ṣeto awọn igbesẹ ti o ni ere, ti inawo wọn ko si pọ, nipa gbingbin ati kikore gbongbo paki. Aṣeyori yi da lori awọn irin-iṣẹ ti a fi n se akojọpọ esi iwadi eleyi ti wọn lo lati fi ṣe abojuto lati mọ bi ọna titun iṣelọpọ na ṣe dara to (eleyi si pẹlu lilo awọn ohun elo iṣelọpọ eyi ti o dara jọjọ, awọn ohun a pa kokoro ti ipele wọn ga, ajilẹ, ati awọn ohun ti a fi n pa koriko, ati lilo ọna igbalode lati fi gbin paki) bi wọn ko ṣe ki n gbọn ni lowo lọ, bi wọn ṣe ni ere lori to, ati bi ilana iselọpọ naa se dara to nigbati a ba fi we ilana iselọpọ ti atijọ nibiti a ti ṣe agbekalẹ awọn iru awọn nkan bayi, nipasẹ iṣẹ akanṣe yi. Afihan ati idi Igbelewọn Iyẹfun Paki ti o dara jọjọ ti o ti ipasẹ ajọsepọ IFAD ati IITA w’aye se afihan gbingbin igi paki ni ona igbalode ati kikore awọn gbongbo paki tutu, lati ọdun 2015/2016 fun awọn agbẹ ti wọn wa ninu eto akanṣe iyẹfun paki eyi ti o dara jọjọ, lati ṣe agbeyẹwo rẹ. Idi isagbejade kẹrin ti abojuwo ati igbelewọn (M&E) ti iṣẹ akanṣe iyẹfun paki eleyi ti o dara jọjọ ni lati se afiwe larin awọn inawo ati anfaani ti ayipada titun (gbingbin ati kikore ni ọna igbalode) pẹlu gbingbin ati kikore paki ni ọna atijọ alafọwọṣe. A se idiwọn ati afiwe ayipada titun yi pẹlu alafọwọṣe gbingbin ati kikore paki nipa imunadoko inawo, nini ere ati iṣelọpọ paki alailẹgbẹ. Ilana Iwadi Ifọrọwanilẹnuwo awọn onifitonileti ti wọn se koko (KII) ati ilana-iṣẹ eto iṣuna owo, eyi ti ko pe ni a lo lati fi se ayẹwo imunadoko inawo, nini ere ati iṣẹ iṣelọpọ paki alailẹgbẹ. A ṣe ifọrọwanilẹnuwo yi pẹlu awọn agbẹ ti wọn ti lo irinṣẹ igbalode lati fi gbin ati lati fi kore, ki a ba le mọ iwoye wọn. Ilana-iṣẹ eto iṣuna owo, eyi ti ko pe ni a lo lati fi ṣe afiwe inawo ati anfaani ayipada titun, pẹlu gbingbin ati kikore alafowose. Afiwe yi da lori esi iwadi ti a ri gba laini idiwo lori ilana titun ti a gba lati ọdọ awọn agbẹ ti wọn n lo ọwọ lati fi gbin ati lati fi kore. Ilana-iṣẹ eto iṣuna owo oniha kan Ilana-iṣẹ eto iṣuna owo oniha kan je ilana fun igbero ati ipinnu ṣiṣe ti a lo, lati fi ṣe afiwe inawo ati anfaani ti o wa ninu awọn ilana miran ti o koju si ṣiṣe ise-ọgbin. O da lori awọn ayipada nipa owo ti a n pa wọle ati nipa inawo, eleyi ti yi o je esi nigbati a ba lo ilana miran. Nitorina, gbogbo awọn ọna atijo ti ere fi n wọle lori ise-ọgbin ti kii yipada, ni a le fi oju fo laifoya. Ni kukuru, Ilana-iṣẹ eto iṣuna owo oniha kan fi aye gba wa lati le mọ ipa ti igbese ti a gbe yoo se ni ere to lori idawole wa, ati ni pato, lati mo ere ti a o ri lori gbogbo ogbin oko wa. Ilana-iṣẹ eto iṣuna owo oniha kan ni a lo lati fi mọ ati lati fi ṣe afiwe nini ere ninu iṣelọpọ paki, nigbati a ṣe afiwe ọna igbalode ati ọna alafọwọṣe. Ilana naa pese awọn alaye pato lori awọn ohun ti a n ko wọ inu oko lati lo, ati inawo, awọn ohun ti a n ko jade lati inu oko ati idiyele wọn, ati iyatọ ti o wa larin inawo ati pipa owo wọle fun awọn agbẹ, eleyi ti a le pe ni ere. Eto iṣuna owo lori iyatọ ti o wa larin inawo ati pipa owo wọle ṣe ayewo ere ti o n wọle si ori awọn ohun elo eyi ti awọn agbẹ lo, awọn ohun elo naa ni awọn oṣiṣẹ ti wọn lo, awọn ohun elo ti a fi owo ra, bi ajilẹ, ogun apa kokoro ati epo, ati awọn ohun iṣelọpọ miran ti a ko wọ inu oko. Ninu ilana yi ni a ti ri aba inawo ati ti ere eyi ti o da lori akoko iṣelọpọ paki ni ọdun 2015/2016. Ọrọ ipilẹ Ere jije ati ona ti a file din inawo ku Okowo Gbaguda:

Upload: others

Post on 22-Oct-2020

0 views

Category:

Documents


0 download

TRANSCRIPT

  • Iṣẹ Akanṣe Alasopọ nipa Iwulo Iyẹfun Paki ti o dara jọjọ, jẹ eleyi ti Ajọ Isuna awon Orile-ede fun Idagbasoke Iṣẹ-ọgbin (IFAD) se atilẹyin rẹ, nigbati Ajọ tinse iwadi fun ise ogbin ni ile Adulawo si jẹ adari rẹ. Iṣẹ Akanṣe Alasopọ Iwulo Iyẹfun Paki, eyi ti o dara jọjọ, nii lọkan lati fidi mulẹ ni orilẹ-ede Naijiria. Ni ilakaka lati ri wipe ilepa re wa si imuṣẹ, ati lati sọ ilepa naa di nla, iṣẹ akanṣe naa ti ṣeto awọn igbesẹ ti o ni ere, ti inawo wọn ko si pọ, nipa gbingbin ati kikore gbongbo paki. Aṣeyori yi da lori awọn irin-iṣẹ ti a fi n se akojọpọ esi iwadi eleyi ti wọn lo lati fi ṣe abojuto lati mọ bi ọna titun iṣelọpọ na ṣe dara to (eleyi si pẹlu lilo awọn ohun elo iṣelọpọ eyi ti o dara jọjọ, awọn ohun a pa kokoro ti ipele wọn ga, ajilẹ, ati awọn ohun ti a fi n pa koriko, ati lilo ọna igbalode lati fi gbin paki) bi wọn ko ṣe ki n gbọn ni lowo lọ, bi wọn ṣe ni ere lori to, ati bi ilana iselọpọ naa se dara to nigbati a ba fi we ilana iselọpọ ti atijọ nibiti a ti ṣe agbekalẹ awọn iru awọn nkan bayi, nipasẹ iṣẹ akanṣe yi.

    Afihan ati idi IgbelewọnIyẹfun Paki ti o dara jọjọ ti o ti ipasẹ ajọsepọ IFAD ati IITA w’aye se afihan gbingbin igi paki ni ona igbalode ati kikore awọn gbongbo paki tutu, lati ọdun 2015/2016 fun awọn agbẹ ti wọn wa ninu eto akanṣe iyẹfun paki eyi ti o dara jọjọ, lati ṣe agbeyẹwo rẹ. Idi isagbejade kẹrin ti abojuwo ati igbelewọn (M&E) ti iṣẹ akanṣe iyẹfun paki eleyi ti o dara jọjọ ni lati se afiwe larin awọn inawo ati anfaani ti ayipada titun (gbingbin ati kikore ni ọna igbalode) pẹlu gbingbin ati kikore paki ni ọna atijọ alafọwọṣe. A se idiwọn ati afiwe ayipada titun yi pẹlu alafọwọṣe gbingbin ati kikore paki nipa imunadoko inawo, nini ere ati iṣelọpọ paki alailẹgbẹ.

    Ilana IwadiIfọrọwanilẹnuwo awọn onifitonileti ti wọn se koko (KII) ati ilana-iṣẹ eto iṣuna owo, eyi ti ko pe ni a lo lati fi se ayẹwo imunadoko inawo, nini ere ati iṣẹ iṣelọpọ paki alailẹgbẹ. A ṣe ifọrọwanilẹnuwo yi pẹlu awọn agbẹ ti wọn ti lo irinṣẹ igbalode lati fi gbin ati lati fi kore, ki a ba le mọ iwoye wọn. Ilana-iṣẹ eto iṣuna owo, eyi ti ko pe ni a lo lati fi ṣe afiwe inawo ati anfaani ayipada titun, pẹlu gbingbin ati kikore alafowose. Afiwe yi da lori esi iwadi ti a ri gba laini idiwo lori ilana titun ti a gba lati ọdọ awọn agbẹ ti wọn n lo ọwọ lati fi gbin ati lati fi kore.

    Ilana-iṣẹ eto iṣuna owo oniha kanIlana-iṣẹ eto iṣuna owo oniha kan je ilana fun igbero ati ipinnu ṣiṣe ti a lo, lati fi ṣe afiwe inawo ati anfaani ti o wa ninu awọn ilana miran ti o koju si ṣiṣe ise-ọgbin. O da lori awọn ayipada nipa owo ti a n pa wọle ati nipa inawo, eleyi ti yi o je esi nigbati a ba lo ilana miran.

    Nitorina, gbogbo awọn ọna atijo ti ere fi n wọle lori ise-ọgbin ti kii yipada, ni a le fi oju fo laifoya. Ni kukuru, Ilana-iṣẹ eto iṣuna owo oniha kan fi aye gba wa lati le mọ ipa ti igbese ti a gbe yoo se ni ere to lori idawole wa, ati ni pato, lati mo ere ti a o ri lori gbogbo ogbin oko wa. Ilana-iṣẹ eto iṣuna owo oniha kan ni a lo lati fi mọ ati lati fi ṣe afiwe nini ere ninu iṣelọpọ paki, nigbati a ṣe afiwe ọna igbalode ati ọna alafọwọṣe. Ilana naa pese awọn alaye pato lori awọn ohun ti a n ko wọ inu oko lati lo, ati inawo, awọn ohun ti a n ko jade lati inu oko ati idiyele wọn, ati iyatọ ti o wa larin inawo ati pipa owo wọle fun awọn agbẹ, eleyi ti a le pe ni ere. Eto iṣuna owo lori iyatọ ti o wa larin inawo ati pipa owo wọle ṣe ayewo ere ti o n wọle si ori awọn ohun elo eyi ti awọn agbẹ lo, awọn ohun elo naa ni awọn oṣiṣẹ ti wọn lo, awọn ohun elo ti a fi owo ra, bi ajilẹ, ogun apa kokoro ati epo, ati awọn ohun iṣelọpọ miran ti a ko wọ inu oko. Ninu ilana yi ni a ti ri aba inawo ati ti ere eyi ti o da lori akoko iṣelọpọ paki ni ọdun 2015/2016.

    Ọrọ ipilẹ

    Ere jije ati ona ti a file din inawo ku

    Okowo Gbaguda:

  • Idalaba awọn ImoranAwọn esi ilana-eto iṣuna owo oniha kan ti fi han gbangba wipe iselọpọ paki nipa ilana igbalode ni ere to pọ lori, ati wipe inawo rẹ ko pọ. Awọn gbongbo paki ti a ri nipa ilana igbalode fẹrẹ jẹ ilọpo meji eyi ti a ri nipa ilana alafọwọṣe, nigbati inawo ti o so mọ gbingbin ati kikore nipa ilana igbalode jẹ idameji owo ti a na nipa ilana alafọwọṣe. Awọn imọran wonyi da lori awọn esi ti a gba ninu ifọrọwanilẹnuwo awọn onifitonileti ti wọn ṣe koko eyi ti a ṣe pẹlu awọn agbẹ, ati itu si wẹwẹ ilana-iṣẹ eto iṣuna owo oniha kan, ti iselọpọ paki, eyi ti a gbe jade si gbangba ninu eto akanṣe iyẹfun paki, eleyi ti o dara jọjọ:-yy Ki awọn agbẹ tẹramọ akitiyan wọn

    lati sọ di mimọ larin awọn agbẹ oni paki, ni riri wipe siso di pupo paki nipa ilana igbalode jẹ itẹwọgba. Iru

    isọdimimọ yi le ṣe ṣe nipa awọn ọjo ti wọn ba n jade lọ lati ṣiṣẹ ni awọn oko wọn, nipa bayi wọn le ṣe agbekalẹ awọn esi ilana-iṣẹ eto iṣuna owo, oniha kan, pipese awọn iwe ilewọ, ki wọn si tun ba wọn sọrọ ni ṣoki.

    yy Itu si wẹwẹ ilana-iṣẹ eto iṣuna owo oniha kan ti fi bi nini ere ṣe n pọ si han nipa lilo ilana igbalode ati imọ ẹrọ fun gbingbin ati kikore ninu iselọpọ paki. O si yẹ ki akitiyan lati gbe iwọn ipolongo ati itankalẹ awọn ẹrọ ti a fi n gbin ati awọn ti a fi n kore soke larin awọn agbẹ onipaki ni awọn agbegbe isẹ akanṣe yi. Ni afikun, iṣẹ akanṣe alasopọ nipa iwulo iyẹfun paki, eleyi ti o dara jọjọ gbọdọ kun agbara awọn agbẹ onipaki, eleyi ti o nii ṣe pẹlu ilana ati imọ iselọpọ ti o dara ju ati awọn

    ilana iṣakoso ere-oko.yy Ki a jẹ ki awọn agbẹ kopa ninu

    ilana-iṣẹ eto iṣuna owo oniha kan yi, pẹlu awọn ti n ṣe iṣẹ iwadi, ni akoko gbingbin ati kikore eyi ti o n bọ wa, ki wọn ba le mọ riri ṣiṣeṣe ọrọ-aje nipa lilo ọna igbalode fun iselọpọ.

    yy Iṣẹ akanṣe alasopọ nipa iwulo iyẹfun paki gbọdọ bẹrẹ lati mọ ati lati sọ di mimọ larin awọn ontaja ti wọn le ṣe ipese iṣẹ gbingbin ati kikore ni ọna igbalode fun awọn agbẹ ti wọn ba ni ifẹ si ni iye owo. Eleyi yoo jẹ ọna ti a fi le ṣe iwuri fun ontaja-iṣẹ ọgbin, eyi ti o ṣẹṣẹ bẹrẹ iṣẹ lati lọ sinu, ati lati so wọn pọ pẹlu awọn ile iṣẹ ti n fi owo ya fun owo ṣiṣe, ati awọn ile iṣe ti n ya awọn eyan ni irinṣẹ lati lo fun iye owo.

    Fun ibeere, e kan si: Project manager: [email protected], Data analyst/Curator: [email protected],

    Communication officer: [email protected]

    http://hqcf.iita.org/ http://hqcf.wordpress.com/

    Tabili 1: Afiwe iṣelọpọ paki nipa gbingbin ni ilana igbalode ati nipa ilana alafọwọṣe ninu eto akanṣe ayipada titun nipa pipese iyẹfun paki eleyi ti o dara jọjọ ni ipinlẹ Ogun.

    gbINgbIN AlAFọwọṣE

    gbINgbIN NIPA IlANA IgbAlODE

    PIPọsI IPIN ọgọruN PIPọsI (%)

    Ere-oko gbongbo ti a ṣẹṣẹ wu kg ha-1 16 22 9.3 38%Idiyelele paki (Naira/ton) 12,000 12,000Owo ti o wọle nipasẹ iṣagbejade (Naira) 192,000 264,000 72,000 38%

    Awọn inawo ti o n yipada ha-1

    Imurasilẹ ilẹ oko 27000 25000 -2,000 -8%Awọn ohun ti a ko wọle ti a ra 38,000 47,000 9,000 24%gbingbin 9,000 4,000 -5,000 -55%Kikore 18,847 7,600 -11,247 -60%Pipa epo alafọwọse 6,000 12,000 6,000 100%Pipa epo nipa lilo ogun 2,000 8,000 6,000 300%Inawo orisirisi miran ati owo gbongbo ati owo ọkọ 9,500 11,000 1,500 16%

    Apapọ inawo ti o n yipada 110,347 114,600 4,253 4%Iyatọ (N per ha-1) 81,653 149,400 67,747 83%