yoruba hymns vr2
DESCRIPTION
freeTRANSCRIPT
Yoruba Hymns4Ji okan mi ba orun ji
4Oluwa mi mo njade lo
5Wa ba mi gbe, ale fere le tan
5Wa s' adura oro
6Olorun Betel eniti
6E mi ba negberun ahon
7Eni nla ni Oluwa
7Bi mo ti ri, lai sawawi
8Olugbala, gbohun mi
9Okan mi nyo ninu Oluwa
9Fi iyin fun Jesu, Olurapada wa
10Gbogbo aye, gbe Jesu ga
11Mo mo pOludande mi mbe
11Ko su wa lati ma ko orin ti igbani
12Eje ka finu didun
12Oluwa emi sa ti gbohun Re
13Si o Olutunu Orun
13Wa sodo Jesu, mase duro
14Isun kan wa to kun feje
14Irapada! itan iyanu
15L oju ale gbat orun wo
16Baba a tun pade l oko Jesu
16Wo Imole larin okun aiye
17Ka to sun Olugbala wa
18Oluw ojo to fun wa pin
18L oju ale gbat orun wo
19Ka to sun Olugbala wa
20Oluw ojo to fun wa pin
21Olorun wa Orun
21Ojo sinmi at ayo
22A be a fe ri O
23Oluwa ojo isimi
23Jesu a fe pade
24Ojo mefa t ise koja
24Eyi l ojo t Oluwa da
25Ayo l ojo simi fun mi
26Emi Olorun alaye
26A f ope f Olorun
27Ojo ibukun y o si ro
27Ijo ti nduro pe
28Oluwa mbo aiye o mi
29Wa eyin olope wa
30Olorun t odun to koja
30Ese won ti da to
31E funpe na kikan
32Krist ki joba Re de
33Jesu yo joba ni gbogbo
33Elese mo nfe bukun
34Jesu agbara mi
35Alaimo ni emi
35Apata aiyeraiye
36Ojo nla l ojo ti mo yan
37Jesu nigba danwo
38Elese e yipada
39Duro, duro fun Jesu
40E maa te siwaju, Kristian ologun
41Gba aiye mi Oluwa
41Gbo okan mi, bi angeli ti nkorin
42Itan iyanu tife! So fun mi lekan si
42Jesu ye, titi aiye
43Ki lo le wese mi nu
44Lowuro ojo ajinde
45Ogo ni fOluwa, to se ohun nla
45Gba ta bOluwa rin n'nu mole oro re
46F ore-ofe Re ba wa gbe
47Ji se Re nde Jesu
47Gbogb ogo iyin ola
48Hosanna sOmo Dafidi
49Gbati mo ri agbelebu
Ji okan mi ba orun jiJi okan mi ba orun ji
Mura si ise oojo re
Ma se ilora ji kutu
K'o san gbese ebo oro
Ro gbogb' ojo t'o fi sofo
Bere si rere se loni
Kiyes' irin re laiye yi
K' o si mura d'ojo nla ni
Gba ninu imole orun
Si tanmole na f'elomi
Je ki ogo Olorun re
Han n'nu iwa ati ise re
Ji gbon 'ra nu, 'wo okan mi
Yan ipo re larin Angel
Awon ti nwon nkorin iyin
Ni gbogbo oru s' Oba wa
Oluwa mi mo njade loOluwa mi mo njade lo
Lati se ise ojo mi
Iwo nikan l' emi o mo
L'oro l' ero, ati n' ise
Ise t'o yan mi l' anu re
Je ki nle se tayotayo
Ki nr' oju Re ni ise mi
K' emi si le f' ife Re han
Dabobo mi lowo 'danwo
K' o pa okan mi mo kuro
L' owo aniyan aiye yi
Ati gbogbo ifekufe
Iwo t'oju Re r' okan mi
Ma wa low' otun mi titi
Ki nma sise lo l'ase Re
Ki nf' ise mi gbogbo fun O
Je ki nreru Re t'o fuye
Ki nma sora nigbagbogbo
Ki nma f' oju si nkan t'orun
Ki nsi mura d'ojo ogo
Ohunkohun t' o fi fun mi
Je ki nle lo fun ogo Re
Ki nfayo sure ije mi
Ki mba O rin titi d' orun
Wa ba mi gbe, ale fere le tanWa ba mi gbe, ale fere le tan
Okunkun nsu, Oluwa ba mi gbe;
Bi oluranlowo miran ba ye
Iranwo alaini, wa ba mi gbe
Ojo aye mi nsare lo sopin
Ayo aye nku, ogo re nwomi
Ayida atibaje ni mo n ri
wo ti ki yipada, wa ba mi gbe
Ma wa leru bOba awon oba
Boninure, wa pelu wosan Re?
Ki Ossi ma kanu fun egbe mi
Wa, ore elese, wa ba mi gbe.
Mo nfe O ri, ni wakati gbogbo
Kilo le swgun esu bore Re?
Talo le se amona mi bi Re?
Nnu banuje atayo ba mi gbe
Pelu bukun Re, eru ko ba mi
Ibi ko wuwo, ekun ko koro,
oro iku da? segun isa da?
Un o segun sibe, biwo ba mi gbe.
Wa ba mi gbe, ni wakati iku
Se mole mi, si toka si orun
Baye ti nkoja, kile orun mo
Ni yiye, ni kiku, wa ba mi gbe
Wa s' adura oroWa s' adura oro
Kunle k' a gbadura
Adura ni opa Kristian
Lati b' Olorun rin
Losan wole labe
Apat' aiyeraiye
Itura ojiji Re dun
Nigba t' orun ba mu
Je ki gbogbo ile
Wa gbadura l' ale
Ki ile wa di t' Olorun
Ati 'bode orun
Nigbat' o d' oganjo
Je ka wi l' emi pe
Mo sun sugbon okan mi ji
Lati ba O sona
Olorun Betel enitiOlorun Betel eniti
O mbo awon Tire
Enit' o mu baba wa la
Ojo aiye won ja
A mu eje at' ebe wa
Wa iwaju 'te Re
Olorun waon baba wa
Ma je Olorun wa
Ninu idamu aiye yi
Ma toju ipa wa
Fun wa ni onje ojo wa
At' aso to ye wa
Na ojiji 'ye Re bo wa
Tit' ajo wa o pin
Ati ni 'bugbe Baba wa
Okan wa o simi
Iru ibukun bi eyi
L' a mbere lowo Re
Iwo o je Olorun wa
At' ipin wa lailai
E mi ba negberun ahonE mi ba negberun ahon
Fun yin Olugbala
Ogo Olorun Oba mi
Isegun Ore Re.
Jesu to seru wa dayo
To mu banuje tan
Orin ni leti elese
Iye atilera.
O segun agbara ese
O da onde sile
Eje Re le weleri mo
Eje Re le weleri mo
Eje Re seun fun mi
O soro, oku gbohun Re
O gba emi titun;
O niro binuje je yayo
Otosi si gbagbo
Odi, e korin iyin re
Aditi , gbohun Re
Afoju, Olugbala de,
Ayaro, fo fayo
Baba mi atolorun mi,
Fun mi ni ranwo Re
Ki nle ro ka gbogbo aye
Ola oruko Re.
Eni nla ni OluwaEni nla ni Oluwa
Ti a yin pupopupo
Ni ilu Olorun wa
Ni oke iwa mimo Re
Didara ni ipo itedo
Ayo gbogbo aiye
Ni Oke Sioni, ni iha ariwa Oba nla
Olorun fi ara han bi abo ninu aafin re
Bi mo ti ri, lai sawawiBi mo ti ri, lai sawawi
Sugbon nitori eje Re
Bo si ti pe mi pe ki nwa
Olugbala, mo de.
Bi mo ti ri, laiduro pe
Mo fe k okan mi mo toto
Sodo Re to le we mi mo
Olugbala, mo de
Bi mo ti ri, bo tile je
Ija lode, ija ninu
Eru lode, eru ninu
Olugbala, mo de
Bi mo ti ri, osi are
Mo si nwa imularada
Iwo le sawotan mi
Olugbala, mo de.
Bi mo ti ri wo o gba mi
wo o gba mi, towo tese
tori mo gba leri Re gbo
Olugbala, mo de.
Bi mo ti ri ife Tire
Lo sete mi patapata
Mo di Tire, Tire nikan
Olugbala, mo de.
Bi mo ti ri, nnu fe nla ni
To fi titobi Re han mi
Nihin yi ati ni oke
Olugbala, mo de.
Olugbala, gbohun miOlugbala, gbohun mi
Gbohun mi, gbohun mi
Mo wa sodo Re, gba mi
Nibi agbelebu
Emi se sugbon O ku
Iwo ku, iwo ku
Fi anu Re pa mi mo
Nibi agbelebu
Oluwa, jo gba mi
Nki yo bi O ninu mo
Alabukun, gba mi
Nibi agbelebu
Ese mi po lapoju
Un o bebe, un o bebe
Iwo li Ona iye
Nibi agbelebu
Ore ofe Re ta gba
Lofe ni lofe ni
Foju anu Re wo mi
Nibi agbelebu
Feje mimo Re we mi
Fi we mi fi we mi
Ri mi sinu ibu Re
Nibi agbelebu
gbagbo lo le fun wa ni
dariji dariji
Mo figbagbo ro mo o
Nibi agbelebu.
Okan mi nyo ninu OluwaOkan mi nyo ninu Oluwa
Tori O je iye fun mi
Ohun Re dun pupo lati gbo
Adun ni lati roju Re
Emi nyo ninu Re
Emi nyo ninu Re
Gba gbogbo lo fayo kun okan mi
Tori emi nyo nnu Re.
O ti pe tO ti nwa mi kiri
gbati mo rin jina sagbo
O gbe mi w asile lapa Re
Nibiti papa tutu wa
Ire atanu Re yi mi ka
Orofe Re nsan bi odo
Emi Re nto, o si nse tunu
O mba mi lo si bikibi
Emi yo dabi Re ni jo kan
Un o seru wuwo mi kale
Titi di gbana un o soloto
Ni sise oso fade Re.
Fi iyin fun Jesu, Olurapada waFi iyin fun Jesu, Olurapada wa
Ki aye kokiki ife Re nla;
Fi iyin fun! eyin Angeli ologo,
Fola atogo fun oruko re,
Boluagutan, Jesu yo to omo Re
Lapa Re lo ngbe won le lojojo
Eyin eniyan mimo ti ngboke Sion
Fi iyin fun pelu orin ayo
Fi iyin fun, Jesu Olurapada wa,
Fun wa, O teje Re sile, O ku
On ni apata, ati reti gbala wa,
Yin Jesu ti a kan magbelebu;
Olugbala tO fara da irora nla
Ti a fi ade egun de lori
Eniti a pa nitori awa eda
Oba ogo njoba titi laelae.
Fi iyin fun, Jesu Olurapada wa
Ki ariwo iyin gba orun kan
Jesu Oluwa njoba lae ati laelae,
Se loba gbogbeyin alagbara
A segun iku; fi ayo royin na ka
Isegun re ha da, isa oku?
Jesu ye ko tun si wahala fun wa mo
tori O lagbara lati gbala
Gbogbo aye, gbe Jesu gaGbogbo aye, gbe Jesu ga
Angel, e wole fun
E mu ade Oba Re wa,
Se lOba awon oba
E se lOba eyin Martyr,
Ti npe ni pepe Re
Gbe gbongbo igi Jese ga
Se lOba awon oba
Eyin iru omo Isreal
Ti a ti rapada
E ki Eni togba yin la
Se lOba awon oba
Gbogbo eniyan elese
Ranti banuje yin
E te kogun yin sese Re
Se lOba awon oba
Ki gbogbo orile ede
Ni gbogbo agbaye
Ki won ki, Kabiyesile
Se lOba awon oba
A ba le pelawon torun
Lati ma juba Re
Ka bale jo jumo korin
Se lOba awon oba
Mo mo pOludande mi mbeMo mo pOludande mi mbe
Itunu nla leyi fun mi!
O mbe, Eni to ku lekan
O mbe, ori iye mi lae.
O mbe lati ma bukun mi
O si mbebe fun mi loke
O mbe lati ji mi nboji
Lati gba mi la titi lae
O mbe, Ore korikosun
Ti yo pa mi mo de opin
O mbe, emi o ma korin
Woli, Alufa, Oba mi
O mbe lati pese aye
YO si mu mi de be layo
O mbe, ogo foruko Re
Jesu okan na titi lae
O mbe, ogo foruko Re
Olugbala kanna titi
A! ayo loro yi fun mi
Mo mo poludande mi mbe
Ko su wa lati ma ko orin ti igbaniKo su wa lati ma ko orin ti igbani
Ogo fOlorun Aleluya
A le fi igbagbo korin na soke kikan
Ogo fOlorun, Aleluya!
Omo Olorun ni eto lati ma bu sayo
Pe ona yi nye wa si
Okan wa nsaferi Re
Nigbo se a o de afin Oba wa ologo
Ogo fOlorun, Aleluya!
Awa mbe nnu ibu ife to ra wa pada
ogo fOlorun Aleluya!
Awa yo fi iye goke lo soke orun
Ogo fOlorun, Aleluya!
Awa nlo si afin kan ti a fi wura ko,
Ogo fOlorun Aleluya!
Nibiti a ori Oba ogo nnu ewa Re
Ogo fOlorun, Aleluya!
Nibe ao korin titun tanu to da wa nde
Ogo fOlorun Aleluya!
Nibe awon ayanfe yo korin yin ti Krist;
Ogo fOlorun, Aleluya!.
Eje ka finu didunEje ka finu didun
Yin Oluwa Olore
Anu Re O wa titi
Lododo dajudaju
On nipa agbara Re
Fimole saye titun
Anu Re, O wa titi
Lododo dajudaju
O mbo gbogbeda laye
O npese fun aini won
Anu re, O wa titi
Lododo dajudaju
O bukun ayanfe Re
Li aginju iparun
Anu re O wa titi
Lododo dajudaju
E je ka finu didun
Yin Oluwa Olore
Anu Re, O wa titi
Lododo dajudaju
Oluwa emi sa ti gbohun ReOluwa emi sa ti gbohun Re
O nso ife Re simi
Sugbon mo fe nde lapa igbagbo
Ki nle tubo sun mo o
Fa mi mora, mora, Oluwa
Sibagbelebu tO ku
Fa mi mora, mora, mora Oluwa
Si beje Re to niye
Ya mi si mimo fun ise Tire
Nipa ore-ofe Re
Je ki nfi okan igbagbo woke
Kife mi si je Tire
A! ayo mimo ti wakati kan
Ti mo lo nibite Re
gba mo ngbadura si O Olorun
Ti a soro bi ore.
Ijinle ife mbe ti nko le mo
Titi un o koja odo
Ayo giga ti emi ko le so
Tit un o fi de simi.
Si o Olutunu OrunSi o Olutunu Orun
Fun ore atagbara Re
A nko, Aleluya
Si O, ife eni tOwa
Ninu Majemu Olorun
A nko, Aleluya
Si O agbara Eni ti
O nwe ni mo, to nwo ni san
A nko, Aleluya
Si O, Oluko atore
Amona wa toto dopin
A nko, Aleluya.
Si O, Eniti Kristi ran
Ade on gbogbo ebun re
A nko, Aleluya
Wa sodo Jesu, mase duroWa sodo Jesu, mase duro
Loro Re lo ti fona han wa
O duro li arin wa loni
O nwi pele pe wa!
Ipade wa yio je ayo
Gbokan wa ba bo lowo ese
Ta o si wa pelu Re Jesu
Nile ayeraye
Jekomode wa! E gbohun Re
Jekokan gbogbo kun fun ayo
Ka si yan Jesu layanfe wa
E ma duro, e wa.
Ranti pO wa pelu wa loni
Feti sofin Re, ko si pamo
Gbo bohun Re ti nwi pele pe
Eyin omo Mi wa.
Isun kan wa to kun fejeIsun kan wa to kun feje
To ti ha Jesu yo
Elese mokun ninu re
O bo ninu ebi
Gba mo figbagbo risun na
Ti nsan fun eje Re
Irapada dorin fun mi
Ti un o ma ko titi
Orin todun ju eyi lo
Li emi o ma ko
Gbati ore-ofe Re ba
Mu mi de odo Re.
Mo gbagbo po pese fun mi
Bi mo tile saiye
Ebun ofe ta feje ra
Ati duru wura
Duro ta tow Olorun se
Ti ko ni baje lae
Ti ao ma fi yin Baba wa
Oruko Re nikan.
Irapada! itan iyanuIrapada! itan iyanu
Ihin ayo fun gbogbo wa
Jesu ti ra dariji fun wa
O san gbese na lorigi
A! elese gba ihin na gbo
Jo gba ihin oto na gbo
Gbeke re le Olugbala re
TO mu igbala fun o wa
O mu wa tinu ku bo si ye
O si so wa domOlorun
Orisun kan si fun elese
We nineje na ko si mo
Ese ki yo le joba wa mo
Bo ti wu ko dan waw o to
Nitori Kristi fi rapada
Pa gbara ese run fun wa
Gba anu tOlorun fi lo o
Sa wa sodo Jesu loni
Tori yo gbenito ba to wa
Ki yi o si da pada laeL oju ale gbat orun wo
L oju ale gbat orun wo
Nwon gbe abirun w odo Re
Oniruru ni aisan won
Sugbon nwon f ayo lo le won
Jesu a de l oj ale yi
A sunmo t awa t arun wa
Bi a ko tile le ri O
Sugbon a mo p O sunmo wa
Olugbala wo osi wa
Omi ko san mi banuje
Omi ko ni ife si O
Ife elomi si tutu
Omi mo pe asan laiye
Beni nwon ko f aiye sile
Omi l ore ti ko se re
Beni nwon ko fi O s ore
Ko s okan ninu wa t o pe
Gbogbo wa si ni elese
Awon t o si nsin O toto
Mo ara won ni alaipe
Sugbon Jesu Olugbala
Eni bi awa n Iwo se
Wo ti ri danwo bi awa
Wo si ti mo ailera wa
Agbar owo Re wa sibe
Ore Re si li agbara
Gbo adura ale wa yi
Ni anu wo gbogbo wa san
Baba a tun pade l oko Jesu
Baba a tun pade l oko Jesu
A si wa teriba lab ese Re
A tun fe gb ohun wa soke si O
Lati wa anu lati korin yin
A yin O fun itoju gbagbogbo
Ojojumo l ao ma rohin se re
Wiwa laye wa anu Re ha ko
Apa Re ki o fi ngba ni mora
O se a ko ye fun ife nla Re
A sako kuro lodo Re poju
Sugbon kikankikan ni O si npe
Nje a de a pada wa le Baba
Nipa oko to bor ohun gbogbo
Nipa ife to ta fe gbogbo yo
Nipa eje ti a ta fun ese
Silekun anu si gbani si leWo Imole larin okun aiye
Wo Imole larin okun aiye
Ma sin mi lo
Okunkun su mo si jina s ile
Ma sin mi lo
To sise mi ohun ehin ola
Emi ko bere sise kan to fun mi
Nigbakan ri, emi ko be O pe
Ma sin mi lo
Beni nko fe O sugbon nigbayi
Ma sin mi lo
Afe aiye ni mo ti nto lehin
Sugbon Jesu ma ranti igbani
Ipa Re l o ti ndi mi mu yo si
Ma sin mi lo
Ninu ere ati yangi aiye
Ma sin mi lo
Titi em o fi ri awon wonni
Ti mo fe tin won ti f aiye sile
Ko to d igba na l ona aiye yi
T iwo ti rin
Ma sin mi lo Jesu Olugbala
Sile Baba
Kin le simi lehin ija aiye
Ninu imole ti ko nipekun
Ka to sun Olugbala wa
Ka to sun Olugbala wa
Fun wa n ibukun ale
A jewo ese wa fun O
Iwo lo le gba wa la
B ile tile ti sududu
Okun ko le se wa mo
Iwo eniti ki sare
Nso awon enia Re
B iparun tile yi wa ka
Ti ofa nfo wa koja
Awon Angeli yi wa ka
Awa o wa l ailewu
Sugbon b iku ba ji wa pa
Ti busun wa d iboji
Je k ile mo wa sodo Re
L ayo at Alafia
N irele awa fara wa
Sabe abo Re Baba
Jesu Wo to sun bi awa
Se orun wa bi Tire
Emi Mimo rado bo wa
Tan mole s okunkun wa
Tit awa o fi ri ojo
Imole aiyeraiye
Oluw ojo to fun wa pin
Oluw ojo to fun wa pin
Okunkun si de l ase Re
Wo la korin owuro wa si
Iyin Re yo male wa dun
A dupe ti Ijo Re ko nsun
B aiye ti nyi lo s imola
O si nsona ni gbogbo aiye
Ko si simi tosan-toru
Bile si tin mo lojojumo
Ni orile at ekusu
Ohun adura ko dake ri
Be lorin iyin ko dekun
Orun to wo fun wa si ti la
S awon eda iwo-orun
Nigbakugb lie nu sin so
Ise yanu Re di mimo
Be Oluwa lai nijoba Re
Ko dabi ijoba aiye
O duro o sin se akoso
Tot eda Re o juba Re
L oju ale gbat orun wo
L oju ale gbat orun wo
Nwon gbe abirun w odo Re
Oniruru ni aisan won
Sugbon nwon f ayo lo le won
Jesu a de l oj ale yi
A sunmo t awa t arun wa
Bi a ko tile le ri O
Sugbon a mo p O sunmo wa
Olugbala wo osi wa
Omi ko san mi banuje
Omi ko ni ife si O
Ife elomi si tutu
Omi mo pea san laiye
Benin won ko f aiye sile
Omi l ore ti ko se re
Beni nwon ko fi O s ore
Ko s okan ninu wa t o pe
Gbogbo wa si ni elese
Awon t o si nsin O toto
Mo ara won ni alaipe
Sugbon Jesu Olugbala
Eni bi awa n Iwo se
Wo ti ri danwo bi awa
Wo si ti mo ailera waAgbar owo Re wa sibe
Ore Re si li agbara
Gbo adura ale wa yi
Ni anu wo gbogbo wa san
Ka to sun Olugbala wa
Ka to sun Olugbala wa
Fun wa n ibukun ale
A jewo ese wa fun O
Iwo lo le gba wa la
B ile tile ti sududu
Okun ko le se wa mo
Iwo eniti ki sare
Nso awon enia Re
B iparun tile yi wa ka
Ti ofa nfo wa koja
Awon Angeli yi wa kaAwa o wa l ailewu
Sugbon b iku ba ji wa pa
Ti busun wa d iboji
Je k ile mo wa sodo Re
L ayo at Alafia
N irele awa fara wa
Sabe abo Re Baba
Jesu Wo to sun bi awa
Se orun wa bi Tire
Emi Mimo rado bo wa
Tan mole s okunkun wa
Tit awa o fi ri ojo
Imole aiyeraiyeOluw ojo to fun wa pinOluw ojo to fun wa pin
Okunkun si de l ase Re
Wo la korin owuro wa si
Iyin Re yo male wa dun
A dupe ti Ijo Re ko nsun
B aiye ti nyi lo s imola
O si nsona ni gbogbo aiye
Ko si simi tosan-toru
Bile si tin mo lojojumo
Ni orile at ekusu
Ohun adura ko dake ri
Be lorin iyin ko dekun
Orun to wo fun wa si ti la
S awon eda iwo-orun
Nigbakugb lie nu sin so
Ise yanu Re di mimo
Be Oluwa lai nijoba Re
Ko dabi ijoba aiye
O duro o sin se akoso
Tot eda Re o juba Re
Olorun wa Orun
Olorun wa Orun
T o fi ojo mefa
Da nkan gbogbo ti mbe laiye
Simi n ijo keje
O pase k a bowo
Fun ojo isinmi
Ibinu Re tobi pupo
S awon t o rufin yi
Awon baba nla wa
Ti ku nin okunkun
Nwon je ogbo aborisa
Nwon ko mo ofin Re
Awa de Oluwa
Gege bi ase Re
Lehin ise ijo mefa
Lati se ife Re
Mimo l ojo oni
O ye ki a sinmi
K a pejo ninu ile Re
K a gbo ro mimo ReIsinmi nla kan ku
F awon enia Re
Om Olorun Alabukun
Mu wa de sinmi Re
Ojo sinmi at ayo
Ojo sinmi at ayo
Ojo inu didun
Ogun fun ibanuje
Ojo dida julo
Ti awon eni giga
Niwaju ite Re
Nko mimo mimo mimo
S eni Metalokan
L ojo yi ni mole la
Nigba dida aiye
Ati fun igbala wa
Kristi jinde loni
L ojo oni l Oluwa
Ran Emi t orun wa
Ojo ologo julo
T o ni mole pipe
Orisun tura ni O
L aiye aginju yi
L ori Re bi ni Pisga
L a nwo le ileri
Ojo ironu didun
Ojo ife mimo
Ojo ajinde lati
Aiye si nkan orun
L oni s ilu t are mu
Ni Manna t orun bo
Si ipejopo mimo
N ipe fadaka ndun
Nibiti Ihin-rere
Ntan imole mimo
Omi iye nsan jeje
Ti ntu okan lara
K a r ore-ofe titun
L ojo simi wa yi
K a si de simi t o ku
F awon alabukun
Nibe k a gbohun soke
Si Baba at Omo
Ati si Emi Mimo
N iyin Metalokan
A be a fe ri O
A be a fe ri O
Ojo simi rere
Gbogbo ose ama wipe
Iwo o ti pe to
O ko w ape Kristi
Jinde ninu oku
Gbogbo ose ama wipe
Iwo o ti pe to
O so t ajinde waGege bi ti Jesu
Gbogbo ose ama wipe
Iwo o ti pe to
Iwo so t isimi
T ilu Alafia
T ibukun enia mimo
Iwo o tip e to
Oluwa ojo isimi
Oluwa ojo isimi
Gbo ti wa pelu wa loni
A wa pade fun adura
A fe gb oro t o fi fun wa
Isimi t aye yi rorun
Sugbon isimi t ohun dun
Lala okan wa fe jo na
T a simi lailese da
Ko si ja ko si dagiri
Ko s aniyan bi t aiye yi
T y o dapo mo ikorin wa
T o nt ete aiku jade wa
Bere ojo t a ti nreti
Afemoju re l a fe riA fe yo lona ise yiK a sun n iku k a ji l ayo
Jesu a fe pade
Jesu a fe pade
L ojo Re mimo yi
A si y ite Re ka
L ojo Re mimo yi
Wo ore wa orun
Adura w ambo wa
Bojuwo emi wa
L ojo Re mimo yi
A ko gbodo lora
L ojo Re mimo yi
Li eru a kunle
L ojo Re mimo yi
Ma taro ise wa
K iwo k o si ko wa
K a sin O b o ti ye
L ojo Re mimo yi
A teti s oro Re
L ojo Re mimo yi
Bukun oro t a gbo
L ojo Re mimo yi
Baw a lo gba t a lo
F ore igbala Re
Si aiya wa gbogbo
L ojo Re mimo yi
Ojo mefa t ise koja
Ojo mefa t ise koja
Okan t isimi sib ere
Wa okan mi si simi re
Yo s ojo t Olorun busi
Ki ronu at ope wan de
Bi ebo turari s orun
K o le fa inu didun wa
T o je t eni t o mo nikan
Ibale aiya orun yi
L eri isimi t o l ogo
T o wa fun enia mimo
Opin aniyan at aisan
Olorun a yo si se Re
L oniruru t ogbo t otun
A fi yin ro anu t o lo
A ni reti s eyi ti mbo
F oni sisin mimo jale
K o si se inu didun ni
B o ti dun lati l ojo yi
Nireti okan ailopin
Eyi l ojo t Oluwa da
Eyi l ojo t Oluwa daO pe gba na ntire
K orun k o yo k aiye k o yo
K iyin yi te na ka
Loni o jinde nu oku
Ijoba Satan tu
Won mimo tan segun Re ka
Nwon nsoro yanu Re
Hosanna si Oba t a yan
S Omo mimo Dafid
Oluwa jo sokale wa
T Iwo t igbala Re
Abukun l Oluwa t o wa
N ise ore-ofe
T o wa l oruko Baba Re
Lati gba ran wa la
Hosanna li ohun goro
L orin Ijo t aiye
Orin t oke orun lohun
Yio dun ju be lo
Ayo l ojo simi fun mi
Ayo l ojo simi fun mi
At agogo at iwasu
Gbat a ba mi nnu banuje
Awon lo nmu inu mi dun
Ayo si ni wakati na
Ti mo lo nnu agbala Re
Lati mo adun adura
Lati gba manna oro ReAyo ni idahun Amin
T o gba gbogbo ile na kan
Lekokan l o ndun t o nrole
O nkoja lo sodo Baba
B aiye fe f agbara de mi
Mo ise ijo mefa re
Oluwa jot u ide na
K o so okan mi d omnira
Emi Olorun alaye
Emi Olorun alaye
Nnu ekun ore-ofe Re
Nibit ese enia tit e
Sokale sori iran wa
F ebun ahon okan ife
Fun wa lati soro fe Re
K ibukun at agbara Re
Ba l awon to ngbo oro na
K okun kase ni bibo Re
Ki darudapo di tito
F ilera f okan ailera
Je ki anu bori binu
Emi Olorun jo peseGbogbo aiye fun Oluwa
Mi si won b afefe oro
K okan okuta le soji
Baptis gbogb orile ede
Rohin segun Jesu yika
Yin oruko Jesu logo
Tit araiye yio jewo Re
A f ope f Olorun
A f ope f Olorun
L okan ati ohun wa
Eni s ohun yanu
Nnu Enit araiye nyo
Gbat a wa l omowo
On na l o ntoju wa
O si nf ebun ife
Se toju wa sibe
Oba onibore
Ma fi wa sile lailai
Ayo ti ko lopin
On bukun yo je tiwa
Pa wa mo nnu ore
To wa gb a ba damu
Yow a ninu ibi
Laiye ati l orun
K a f iyin on ope
F Olorun Baba Omo
Ati Emi Mimo
Ti o ga julo l orun
Olorun kan lailai
T aiye at orun mbo
Be l o wa d isiyi
Beni yo wa lailai
Ojo ibukun y o si ro
Ojo ibukun y o si ro
Ileri ife l eyi
A o ni itura didun
Lat odo Olugbala
Ojo ibukun ! Ojo ibukun l a nfe
Iri anu nse yi wa ka sugbon ojo l a ntoro
Ojo ibukun y o si ro
Isoji iyebiye
Lori oke on petele
Iro opo ojo mbo
Ojo ibukun y o si ro
Ran won si wa Oluwa
Fun wa ni itura didun
Wa f ola fun oro Re
Ojo ibukun y o si ro
Iba je le ro loni
B a ti njewo f Olorun wa
T a npe oruko Jesu
Ijo ti nduro pe
Ijo ti nduro pe
Lati ri Oluwa
O si wa bakanna sibe
Ko s alabaro fun
Odun nyi lu odun
Ojo ngori ojo
Sibe lairi Oluwa re
O wa ninu ofo
Ma bo Jesu ma bo
Awon mimo laiye
Opo won l o ti ku
Bi won si tin lo lokankan
L a nte won gbe ra wonA te won lati sun
Ki se l ainireti
A te won lati reju ni
K ile ogo to mo
Ma bo Jesu ma bo
Awon ota npo si
Agbara Esu nga
Ogun ngbona igbagbo nku
Ife si di tutu
Yo ti pe to Baba
Oloto Olore
Wo ki y o koya omije
At eje Ijo Re
Mabo Jesu ma bo
A nfe gbo ohun Re
A nfe f oju kan O
K a le gba ade at ogo
B a ti ngb ore Re
Jo wa m ese kuro
At egun at eri
Ko si so aiye osi yi
D aiye rere Tire
Ma bo Jesu ma boOluwa mbo aiye o mi
Oluwa mbo aiye o miOke yo sidi n ipo won
At irawo oju orun
Yo mu imole won kuro
Oluwa mbo bakanna ko
Bi o ti wa n irele ri
Odo aguntan ti a pa
Eni iya ti o si ku
Oluwa mbo li eru nla
L owo ina pelu ija
L or iye apa Kerubu
Mbo onidajo araiye
Eyi ha li eniti nrin
Bi ero l opopo aiye
Ti a se nunibibi si
A Eniti a pa l eyi
Ika b e wo nu apata
B e wo nu iho lasan ni
Sugbon igbagbo t o segun
Yo korin pe Oluwa de
Wa eyin olope wa
Wa eyin olope wa
Gbe orin ikore ga
Ire gbogbo ti wole
K otutu oye to de
Olorun Eleda wa
Lo ti pese f aini wa
Wa ka re le Olorun
Gbe orin ikore ga
Oko Olorun l aiye
Lati s eso iyin Re
Alikama at epo
Ndagba f aro tab ayo
Ehu na ipe tele
Siri oka nikehin
Oluwa kore mu wa
Je eso rere fun O
Ntori Olorun wa mbo
Yo si kore Re sile
On o gbon gbogbo panti
Kuro l oko Re njo na
Yo f ase f awon Angel
Lati gba epo s ina
Lati ko alikama
Si aba Re titi lai
Beni ma wa Oluwa
Si ikore ikehin
Ko awon enia Re jo
Kuro l ese at aro
So won di mimo lailai
Ki nwon le ma ba O gbe
Wa t Iwo t Angeli ReGbe orin ikore ga
Olorun t odun to kojaOlorun t odun to kojaIret eyi ti mbo
Ib isadi wa ni iji
At ile wa lailaiLabe ojiji ite Re
L awon enia Re ngbe
Tito l apa Re nikanso
Abo wa si daju
K awon oke ko to duro
Tabi k a to d aiye
Lailai Iwo ni Olorun
Bakana l ailopin
Egberun odun loju Re
Bi ale kan l o ri
B iso kan l afemojumo
Kio run ko to la
Ojo wa bi odo sisan
Opo l o si ngbe lo
Nwon nlo nwon di eni gbagbe
Bi ala ti a nro
Olorun t odun t o koja
Iret eyi ti mboMa s abo wa gba yonu de
At ile wa lailai
Ese won ti da to
Ese won ti da to
Ti nduro ni Sion
Awon t o mu hin gbala wa
Awon to f ayo han
Ohun won ti wo to
Ihin na ti dun to
Sion w Olorun Oba re
Bo ti segun nihin
Eti wa ti yo to
Lati gboro ayo
Woli Oba ti duro de
Nwon wan won ko si ri
Oju wa ti yo to
T o ri mole orun
Oba woli nwon wa titi
Nwon si kun won ko ri
Oluwa f ipa han
Lori gbogbo aiye
Ki gbogbo orile ede
W Oba Olorun won
E funpe na kikan
E funpe na kikan
Ipe ihinrere
K o dun jake jado
L eti gbogbo eda
Odun idasile ti de
Pada elese e pada
Fun pe t Odagutan
T a ti pa s etutu
Je ki agbaiye mo
Agbara eje Re
Odun idasile ti de
Pada elese e pada
Enyin eru ese
E so ra nyin d omo
Lowo Kristi Jesu
E gba omnira nyin
Odun idasile ti de
Pada elese e pada
Olori Alufa
L Olugbala ise
O fi ra Re rubo
Arukun aruda
Odun idasile ti de
Pada elese e pada
Okan alare wa
Simi lara Jesu
Onirobinuje
Tujuka si ma yo
Odun idasile ti de
Pada elese e pada
Krist ki joba Re de
Krist ki joba Re de
Kia se Re bere
F opa-irin Re fo
Gbogbo ipa ese
Ijoba ife da
Ati t Alafia
Gbawo ni irira
Yio tan bi t orun
Akoko na ha da
T ote yio pari
Ika at ireje
Pelu ifekufe
Oluwa jo dide
Wa n nu agbara Re
Fi ayo fun awa
Ti o nsaferi Re
Eda ngan oko Re
Koko nje agbo Re
Iwa tiju pupo
Nfihan pe fe tutu
Okun bole sibe
Ni ile keferi
Dide Rawo oro
Dide mase wo mo
Jesu yo joba ni gbogbo
Jesu yo joba ni gbogbo
Ibit a ba le ri orun
Joba Re yo tan kakiri
Joba Re ki o nipekun
On lao ma gbadura si
Awon oba yo se lOba
Oruko Re b orun didun
Yo ba ebo oro goke
Gbogbo oniruru ede
Yo fi fe Re korin didun
Awon omode o jewo
Pe bukun won t odo Re wa
Bukun po nibit On joba
A tu waon onde sile
Awon alare ri simi
Alaini si ri bukun gba
Ki gbogbo eda ko dide
Ki nwon fola fun Oba wa
K Angel tun wa t awon torin
Ki gbogb aiye jumo gberin
Elese mo nfe bukun
Elese mo nfe bukun
Onde mo fe d omnira
Alare mo nfe simi
Olorun sanu fun mi
Ire kan emi ko ni
Ese sa lo yi mi ka
Eyi nikan l ebe mi
Olorun sanu fun mi
Irobinuje okanNko gbodo gboju soke
Iwo sa mo edun mi
Olorun sanu fun mi
Okan ese mi yi nfe
Sa wa simi laya Re
Lat oni mo di Tire
Olorun sanu fun mi
Enikan mbe lor ite
Ninu Re nikansoso
Nireti at ebe mi
Olorun sanu fun mi
On o gba oran mi ro
On ni Alagbawi mi
Nitori Tire nikan
Olorun sanu fun mi
Jesu agbara mi
Jesu agbara mi
Iwo laniyan mi
Emi fi igbagbo woke
Iwo lo ngb adura
Je ki nduro de O
Kin le se ife Re
Ki Iwo Olodumare
Ko so mi di otun
Fun mi l okan rele
Ti ma se ara re
Ti ntemole to ko nani
Ikekun Satani
Okan t ara re mo
Irora at ise
To nfi suru at igboiya
Ru Agbelebu re
Fun mi l eru orun
Oju to mu hanhan
T yo wo O ngb ese sunmole
Ko ri b Esu ti nsa
Fun mi ni emi ni
To ti pese tele
Emi to nduro gangan lai
To nf adura sona
Mo gbekel oro Re
Wo lo leri fun miIranwo at igbala mi
Yo t odo Re wa se
Sa je kin le duro
K ireti mi ma ye
Tit Iwo o fi m okan mi
Wo nu isimi Re
Alaimo ni emi
Alaimo ni emi
Olorun Oluwa
Emi ha gbodo sunmo O
T emi t eru ese
Eru ese yi npa
Okan buburu mi
Yio ha si ti buru to
L oju Re mimo ni
Emi o ha si kuNi alainireti
Mo r ayo ninu iku Re
Fun otosi b emi
Eje ni ti o ta
T ise or ofe Re
Le w elese t o buruju
Le m okan lile ro
Mo wole l ese Re
Jo k o dariji mi
Nihin l emi o wa titi
Wo o wipe Dide
Apata aiyeraiye
Apata aiyeraiye
Se ibi isadi miJe ki omi on eje
T I san lati iha Re
Se iwosan f ese mi
K o si so mi di mimo
K ise ise owo mi
L o le mu ofin Re se
B itara mi ko l are
T omije mi nsan titi
Nwon ko to fun etutu
Wo nikan l o le gbala
Ko s ohun ti mo mu wa
Mo ro mo agbelebu
Mo wa k o d as obo mi
Mo nwo O fun iranwo
Mo wa sib orison ni
We mi Olugbala mi
Gbati emi mi ban lo
T iku ba p oju mi de
Ti mba nlo s aiye aimo
Ti nri O n ite dajo
Apata aiyeraiye
Se ibi isadi mi
Ojo nla l ojo ti mo yan
Ojo nla l ojo ti mo yan
Olugbala l Olorun mi
O ye ki okan mi ma yo
Ko sir o ihin na ka le
Ojo nla l ojo na
Ti Jesu we ese mi nu
O ko mi kin ma gbadura
Kin ma sora ki nsi ma yoOjo nla l ojo na
Ti Jesu we ese mi nu
Ise igbala pari na
Mo di t Oluwa mi loni
On lo pe mi ti mo si je
Mo f ayo jipe mimo na
Ojo nla l ojo na
Ti Jesu we ese mi nu
O ko mi kin ma gbadura
Kin ma sora ki nsi ma yo
Ojo nla l ojo na
Ti Jesu we ese mi nu
Eje mimo yi ni mo je
F Enit o ye lati feran
Je k orin didun kun le Re
Nigba mo ban lo sin nibe
Ojo nla l ojo na
Ti Jesu we ese mi nu
O ko mi kin ma gbadura
Kin ma sora ki nsi ma yo
Ojo nla l ojo na
Ti Jesu we ese mi nu
Simi aiduro okan mi
Simi le Jesu Oluwa
Tani je wipe aiye dun
Ju odo awon Angeli
Ojo nla l ojo na
Ti Jesu we ese mi nu
O ko mi kin ma gbadura
Kin ma sora ki nsi ma yo
Ojo nla l ojo na
Ti Jesu we ese mi nu
Enyin orun gbo eje mi
Eje mi ni ojojumo
Em o ma do dotun titi
Iku yo fi mu mi re le
Ojo nla l ojo na
Ti Jesu we ese mi nu
O ko mi kin ma gbadura
Kin ma sora ki nsi ma yo
Ojo nla l ojo na
Ti Jesu we ese mi nu
Jesu nigba danwo
Jesu nigba danwo
Gbadura fun mi
Kemi ma ba se O
Ki nsi sako lo
Gba mba nsiyemeji
Ko bojuwo mi
Keru tab isaju
Ma mu mi subu
Baiye ba si nfa mi
Pelu adun re
Tohun sura aiye
Fe han mi lemo
Jo mu Getsemane
Wa s iranti mi
Tabi irora Re
Loke Kalfari
Bo bap on mi loju
Ninu ife Re
Da ibukun Re le
Ori ebon a
Ki nfara mi fun O
Lori pepe Re
Bara ko ago na
Igbagbo yo mu
Gba mo ban re boji
Sinu ekuru
T ogo ogun si nko
Leti bebe na
Ngo gbekel oto Re
N ijakadi ku
Oluwa gbemi mi
Siye ailopinElese e yipada
Elese e yipada
Ese ti e o fi ku
Eleda nyin ni mbere
To fe ki e ba On gbe
Oran nla ni o mbi nyin
Ise owo Re ni nyin
A enyin alailope
Ese t e o ko fe Re
Elese e yipadaEse ti e o fi ku
Olugbala ni mbere
Enit o gb emi nyin la
Iku Re yo jasan bi
E o tun kan mo gi bi
Eni rapada ese
Ti e o gan ore Re
Elese e yipada
Ese ti e o fi ku
Emi Mimo in mbere
Ti nf ojo gbogbo ro nyin
E ki o ha gb oro Re
E o ko iye sibe
A ti nwa nyin pee se
Te mbi Olorun ninu
Iyemeji ha nse nyin
Pe ife ni Olorun
E ki o ha gb oro Re
K e gba ileri Re gbo
WOluwa nyin lodo nyin
Jesu nsun womije Re
Eje Re pelu nke pe
Ese ti e o fi ku Duro, duro fun JesuDuro, duro fun Jesu,
Eyin omogun Krist:
Gbe asia Re soke
A kogbodo fe ku;
Lati segun de segun
Ni yo ma to ogun Re;
Titao segun gbogbota,
Ti Krist yo jOluwa
Duro, duro fun Jesu
Feti sohun ipe
Jade lo soju ija
Loni ojo nla Re:
Enyin akin ti nja fun
Larin ainiye ota,
Nu ewu en igboya
Dojuko agbara.
Duro, duro fun Jesu,
Duro lagbara Re
Ipa enia ko to
Ma gbekele tire:
Fihinrere hamora
Ma sona, ma gbadura
Bise tab ewu ba pe
Ma se alai de be.
Duro, duro fun Jesu
Ija na ki yo pe;
Oni, ariwo ogun,
Ola, orin segun,
Eni to ba si segun,
Yo gba ade iye
Yo ma ba Oba Ogo
Joba titi lailaiAmin
E maa te siwaju, Kristian ologun
E maa te siwaju, Kristian ologun
Maa tejumo mo Jesu to mbe niwaju;
Kristi Oluwa wa ni Balogun wa
Wo! asia re wa niwaju ogun.
E ma te siwaju Kristian ologun
Sa tejumo Jesu to mbe niwaju.
Ni oruko Jesu ogun esu sa,
Nje Kristian ologun, ma nso si segun;
Orun apadi mi ni hiho iyin
Ara gbohun yin ga, gborin yin soke.
Bi egbe ogun nla, nIjo Olorun,
Ara, a nrin lona tawon mimo
A ko ya wa nipa, egebe kan ni wa
Okan Leko nife ati nireti.
Ite atijoba wonyi le parun,
Sugbon Ijo Jesu yo wa titi lai,
Orun apadi ko le bor ijo yi
A nileri Kristi, eyi ko le ye.
E ma ba ni kalo, eyin eniyan;
Dohun yin po mo, lorin isegun,
Ogo, iyin, ola fun Kristi Oba
Eyi ni yo ma je orin wa titi.
Gba aiye mi Oluwa Gba aiye mi Oluwa,
Mo ya si mimo fun O
Gba gbogbo akoko mi
Ki nwon kun fin iyin Re.
Gba owo mi, ko si je
Ki nma lo fun ife Re;
Gba ese mi, ko si je
Ma jise fun O titi
Gba ohun mi, je ki nma
Korin fOba mi titi;
Gba ete mi, je ki wom
Ma jise fun o titi.
Gba wura, fadaka mi
Okan nki o da duro;
Gba ogbon mi, ko si lo
Gege bi o ba ti fe.
Gba fe mi. fi se Tire;
Kio tun je temi mo;
Gb okan mi, Tire n ise
Ma gunwa nibe titi.
Gba feran mi, Oluwa
Mo fi gbogbo re fun O
Gbemi papa; lat oni
Kim je Tire titi lai.
Gbo okan mi, bi angeli ti nkorin
Gbo okan mi, bi angeli ti nkorin
Yika orun ati yika aiye
E gbo bi oro orin won ti dun to
Ti nso gbati ese ki yo si mo.
Angeli Jesu, angel mole
Nwon nkorin ayo pade ero lona
Ba si ti nlo, bee la si ngbo orin won
Wa, arale, Jesu lo ni ke wa
Lokunkun ni a ngb' orin didun won
Ohun orin won ni nfonahan wa
Ohun Jesu ni a n gbo lona rere
Ohun naa ndun bagogo yaye ka
Egbegberun awon to gbo ni si mbo
Mu won wodo Re, Olugbala wa
Isimi de, lehin ise on aare
Ojumo mo, lehin okun aye;
Irin ajo pari, fawon alare
Nwon si ti dorun ibi isimi:
Ma korin nso eyin angeli rere
E ma korin didun ka ba ma gbo;
Titao fi nu omije oju wa nu
Ti ao si ma yo titi lailai.
Itan iyanu tife! So fun mi lekan si
Itan iyanu tife! So fun mi lekan si
Itan iyanu tfe! Ti dun leti kikan
Awon Angeli rohin re, awon oluso si gbagbo
Elese, iwo ki y gbo? Itan iyanu tfe!
Iyanu! Iyanu!
Iyanu! Itan iyanu tife
Itan iyanu tife ! Biwo tile sako
Itan iyanu tife! Sibe o npe loni
Lato oke kalfari, lati orisun didan ni
Lati ise-dale aiye ;itan iyanu tife.
Itan iyanu tife! Jesu ni isimi
Itan iyanu tife! Fun awon oloto
To simi nilu nla orun, Pelawon to saju wa lo
Nwon nko orin ayo orun, itan iyanu tife.
Jesu ye, titi aiye
Jesu ye, titi aiye
Eru iku ko ba ni mo;
Jesu ye; Nitorina
Isa oku ko nipa mo.
Alleluya!
Jesu ye; latoni lo
Iku je ona si iye;
Eyi yo je tunu wa
Gbat akoko iku ba de.
Alleluya!
Jesu ye; fun wa lo ku
Nje Tire ni a o ma se;
A o fokan funfun sin,
A o f ogo fOlugbala.
Alleluya!
Jesu ye; eyi daju
Iku atipa okunkun
Ki yo le ya ni kuro
Ninu ife nla ti Jesu
Alleluya!
Jesu ye; gbogbo joba
Lorun, li aiye, di tire;
E je ki a ma tele,
ki a le joba pelu Re.
Alleluya!
Ki lo le wese mi nuKi lo le wese mi nu,
Ko so, leyin eje Jesu;
Ki ltun le wo mi san,
ko si, leyin eje Jesu.
A! eje yebiye
To mu mi fun bi sno
Ko sisun miran mo,
Ko si lehin eje Jesu
Fun wenumo mi, nko ri
Nkan mi, lehin eje Jesu;
ohun ti mo gbekele,
Fun dariji, leje Jesu.
Etutu fese ko si,
Ko si, lehin eje Jesu;
Ise rere kan ko si,
Ko si, lehin eje Jesu.
Gbogbo igbekele mi,
Ireti mi, leje Jesu;
Gbogbo ododo mi ni
Eje, kiki eje Jesu
Lowuro ojo ajindeLowuro ojo ajinde,
Tara tokan yo pade,
Ekun, kanu on irora
Yo dopin.
Nihin nwo ko le sai pinya
Ki ara ba le sinmi,
Ko si fi idakeroro
Sun fonfon.
Fun gba die ara are yi
La gbe sibi simi re;
Titi di imole oro
Ajinde.
Okan to kanu nisisiyi
To si ngabdura kikan,
Yo bu sorin ayo lojo
Ajinde.
Ara atokan yo dapo
Ipinya ko ni si mo
Nwon o ji laworan Kristi ni
Telorun.
A! ewa na atayo na
Yo ti po to lAjinde!
Yo duro, borun ataiye
Ba fo lo.
Loro ojo ajinde wa
Boji yo m oku re wa;
Baba, iya, omo, ara
Yo pade.
Sdapo ti ofun bayi
Jesu masai ka wa ye
Nnu ku, dajo ka le ro mo
Gbelebu.
Ogo ni fOluwa, to se ohun nlaOgo ni fOluwa, to se ohun nla;
Ifelo mu ko fun wa ni Omo Re,
Eniti O femi Re lele fese wa,
To si silekun iye sile fun wa.
Yin Oluwa, yin Oluwa,
FIyin fun Oluwa!
Yin Oluwa, yin Oluwa,
E yo ni waju Re!
Ka to baba wa lo, Loruko Jesu,
Jeka jo fogo fun Onise yanu.
Irapada kikun, ti eje Re ra,
Fenikeni togba ileri Re gbo;
Enito buruju boba le gbagbo,
Lojukanna yori idari gba.
O sohun nla fun wa, o da wa lola.
Ayo wa di kikun ninu Omo Re;
Ogo ati ewa Irapada yi
Yoya wa lenu gbata ba ri Jesu.
Gba ta bOluwa rin n'nu mole oro reGba ta bOluwa rin n'nu mole oro re,
Ona wa yio ti mole to!
Gba ta ba nse fe Re, on yo ma ba wa gbe,
At awon to ba gbeke won le.
Sa gbekele, ona miran kosi
Lati layo nnu Jesu, jupe ka gbekele.
Ko sohun to le de, loke tabi nile
T'o le ko agbara re loju;
Iyemeji eru, ibanuje, ekun
Kole duro ba ba gbekele.
Ko seru tale ru, ko saro ta le pin
Ti ki yo san ere re fun wa
Kosi arokan mo, tabi ifajuro
Sugbon ibukun baba gbekele.
A ko le fenu so bife re ti po to
Titi a o fara wa rubo
Aanu ti o nfihan, atayo to nfun ni
Je tawon to ba gbeke won le.
Nibi pade ayo ka joko n' ese Re.
Tabi kajo rin ni ona Re.
Oun to so la o se, ibi to wu la o lo;
Kosi beru, ka sa gbekele.F ore-ofe Re ba wa gbe
F ore-ofe Re ba wa gbe
Jesu Olugbala
Ki eni arekereke
K o ma le kolu wa
F ore mimo Re ba wa gbe
Jesu iyebiye
K a ri igbala on iye
Lohun bi nihinyi
Fi bukun Tire ba wa gbe
Oluwa Oloro
Fie bun orun rere Re
Fun wa l opolopo
Fi pamo Tire ba wag be
Iwo Alagbara
K awa k o le sa ota ti
K aiye k o ma de wa
Fi otito Re ba wa gbe
Olorun OloreNinu ponju wa ba wa re
Mu wa fi ori ti
F Alafia Re ba wag beNigbat iku ba de
N iseju na so fun w ape
Igbala nyin ti de
Ji se Re nde Jesu
Ji se Re nde Jesu
Fi agbara Re han
Fohun to le j oku dide
Mu k enia Re gbo
Ji se Re nde Jesu
To orun iku yi
Fi Emi agbara nla Re
Ji okan ti ntogbe
Ji se Re nde JesuMu k ongbe Re gbe wa
Si mu k ebi pa okan wa
Fun onje iye na
Ji se Re nde JesuGbe oruko Re ga
Mu k ife Re kun okan wa
Nipa Emi Mimo
Ji se Re nde JesuRojo itura Re
Ogo yo je Tire nikan
K ibukun je tiwa
Gbogb ogo iyin ola
Gbogb ogo iyin ola
Fun O Oludande
S Eni t awon omode
Ko Hosanna didun
Wo l Oba Israeli
Om Alade Dafid
T O wa l oko Oluwa
Oba Olubukun
Gbogb ogo iyin ola
Fun O Oludande
S Eni t awon omode
Ko Hosanna didun
Egbe awon maleka
Nyin O loke giga
Awa at eda gbogbo
Si dapo gberin na
Awon Hebru lo saju
Pelu imo ope
Iyin adun at orin
L a mu wa waju Re
Si O saju iya Re
Nwon korin iyin won
Wo t a gbega nisiyi
L a nkorin iyin si
Wo gba orin iyin won
Gb adura t a mu wa
Wo ti nyo sohun rere
Oba wa olore
Hosanna sOmo Dafidi
Hosanna sOmo Dafidi
Hosanna e korin
Olubukun leniti mbo
Loruko Oluwa
Hosanna sOmo Dafidi
Legbe Angeli nke
Gbogb eda e jumo gberin
Hosannah sOba wa
Hosanna awon Heberu
Ja imope sona
Hosanna e mu ebun wa
Fit un ona Re se
Tagab tewe nke Hosanna
Kijiya Re to de
Loni a si nko Hosanna
Bo ti njoba loke
Bo ti gba yin won nigbani
Jo gba ebe wa yi
Lorun ka le bAngel korin
Hosanna sOba wa
Gbati mo ri agbelebu
Gbati mo ri agbelebuTi a kan Oba ogo mo
Mo ka gbogbo oro sofo
Mo kegan gbogbo ogo mi
K a ma se gbo pe mo nhale
B o ye n iku Oluwa mi
Gbogbo nkan asan ti mo fe
Mo da sile fun eje Re
Wo lat ori owo ese
B ikanu at ife papo
Banuje atife papo
A fegun se ade ogo
Gbogbo aiye ba je t emi
Ebun abere ni fun mi
Ife nla ti nyanilenu
Gba gbogbo okan emi mi
L owuro Ojo Ajinde
L owuro Ojo Ajinde
Tara tokan yo pade
Ekun kanu on irora
Yo dopin
Nihin won ko le sai pinya
Ki ara ba le simi
Ko si fi idakeroro
Sun fonfon
Fun gba die ara are yi
La gbe sibi simi re
Titi di imole oro
Ajinde
Okan to kanu nisiyi
To si ngbadura kikan
Yo bu sorin ayo lojo
Ajinde
Ara atokan yo dapo
Ipinya ko ni si mo
Nwon o ji laworan Krist, niTelorun
A ewa na at ayo na
Yo tip o to lAjinde
Yo duro, borun at aiye
Ba fo lo
Loro ojo ajinde wa
Boji yo moku re wa
Baba, iya, omo, ara
Yo pade
Si dapo ti o dun bayi
Jesu msai ka wa ye
Nnu ku, dajo ka le ro ma
Gbelebu4