Àrokò pípa lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn törö-...

23
Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkálé Akínlëyç, Muritala Këhìndé Department of Language Education Corona College of Education Lekki [email protected] Ìlò àwôn ìtàkùn ìbánidörêë tàbí ìròyìn törö-fönkálé lórí êrô ayélujára, yálà lórí êrô kõ¸pútà tàbí àwôn êrô ìbánisõrõ ìgbàlódé, ló gbòde kan báyìí. WhatsApp, Facebook àti Yahoo Mail ni àfojúsùn wa nínú iÿë yìí. Àrokò pípa jë õkan pàtàkì lára àwôn ìlànà tí a fi þ báni sõrõ lórí àwôn êrô wõnyí. Látàrí èyí a ÿe àyêwò àwôn àbùdá/àkóónú àrokò pípa, bí àwôn onímõ ìÿaájú ti ÿe là á kalê àti bí wön ti ÿe þ jçyô nínú ìlò àwôn êrô wõnyìí. A ÿe àpèjúwe àrokò pípa gëgë bí ìlànà tó rôrùn láti máa fi báni sõrõ lórí àwôn ìtàkùn ìbánidörêë wõnyìí, dípò kí á máa kô õrõ ránÿë nìkan. A tçpçlç mö àwôn àrokò ìfë, ìgbéyàwó àti ômô bíbí/ìbímô. Àrokò àlùfàýÿá tó gbòde kan láàrin àwôn õdö àti õpõlôpõ ènìyàn ni a fi ÿe ìdánilárayá iÿë yìí. Gbogbo àwôn àrokò tí a lò wá bö sí abë ìsõrí àwôn àrokò ìgbàlódé. Àwôn ìdàgbàsókè tó dé bá àrokò àbáláyé ló ÿe atönà wa níbi iÿë ìwádìí yìí. Ìwádìí yìí fi hàn pé àrokò pípa lórí àwôn ìtàkùn ìbánidörêë tàbí ìròyìn törö-fönkálé ti gbêyç löwö ìlànà àrokò àbáláyé báyìí. Tíörì tí a fi ÿe òpó iÿë yìi ni tíörì

Upload: others

Post on 07-May-2020

3 views

Category:

Documents


0 download

TRANSCRIPT

Page 1: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

Akínlëyç, Muritala Këhìndé

Department of Language Education Corona College of Education Lekki [email protected]

Ìlò àwôn ìtàkùn ìbánidörêë tàbí ìròyìn törö-fönkálé lórí êrô ayélujára, yálà lórí êrô kõ¸pútà tàbí àwôn êrô ìbánisõrõ ìgbàlódé, ló gbòde kan báyìí. WhatsApp, Facebook àti Yahoo Mail ni àfojúsùn wa nínú iÿë yìí. Àrokò pípa jë õkan pàtàkì lára àwôn ìlànà tí a fi þ báni sõrõ lórí àwôn êrô wõnyí. Látàrí èyí a ÿe àyêwò àwôn àbùdá/àkóónú àrokò pípa, bí àwôn onímõ ìÿaájú ti ÿe là á kalê àti bí wön ti ÿe þ jçyô nínú ìlò àwôn êrô wõnyìí. A ÿe àpèjúwe àrokò pípa gëgë bí ìlànà tó rôrùn láti máa fi báni sõrõ lórí àwôn ìtàkùn ìbánidörêë wõnyìí, dípò kí á máa kô õrõ ránÿë nìkan. A tçpçlç mö àwôn àrokò ìfë, ìgbéyàwó àti ômô bíbí/ìbímô. Àrokò àlùfàýÿá tó gbòde kan láàrin àwôn õdö àti õpõlôpõ ènìyàn ni a fi ÿe ìdánilárayá iÿë yìí. Gbogbo àwôn àrokò tí a lò wá bö sí abë ìsõrí àwôn àrokò ìgbàlódé. Àwôn ìdàgbàsókè tó dé bá àrokò àbáláyé ló ÿe atönà wa níbi iÿë ìwádìí yìí. Ìwádìí yìí fi hàn pé àrokò pípa lórí àwôn ìtàkùn ìbánidörêë tàbí ìròyìn törö-fönkálé ti gbêyç löwö ìlànà àrokò àbáláyé báyìí. Tíörì tí a fi ÿe òpó iÿë yìi ni tíörì

Page 2: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

165

The 9 No. 4)

ìbára-çni-ÿe-põ alárokò (Symbolic Interactionist Theory). Àgbálôgbábõ iÿë yìí ló mú wa dábàá pé kí àwa olùkö túbõ kö êkö nipa ÿíÿe àmúlò àrokò orí êrô ayélujára, kí á sì máa lò ó gëgë bí ohùn èlò ìköni ní àwôn ilé-êkö alákõöbêrê àti girama. Bí eléyìí ÿe þ mú àgböyé rôrùn sí i, ni yóò sì tún máa dá wôn lára yá pêlú.

Kókó Õrõ: Àrokò, Ìbánisõrõ, Ayélujára, Ìtàkùn Törö-fönkálé

Ajétúnmôbí (2014) sô pé àrokò pípa je õnà ìbánisõrõ àwôn ìran Yorùbá nínú èyí tí wön ti máa þ ÿàmúlò àwôn ohun èlò ní oníranýran, iye, àwõ tàbí àlòpõ, èyí tó jë pé àwôn tó wà láwùjô ààfin tàbí àwôn tó nímõ ni pa êkö àÿà láwùjô Adúláwõ nìkan ló máa þ mô ìtumõ wôn. Ó tê síwájú láti pe àrokò ní ôgbön ìbánisõrõ àdáyébá (Traditional Information Technology). Oríkì àti àpèjúwe tí Ajétúnmôbí fún àrokò yìí wúni lórí jôjô. Ó sì fìdí rê múlê dájú gbañgba pé, kí wön tó ÿòòÿà la ti þ ÿoóÿá nílê Yorùbá. Ìyçn ni pé, ôgbön àtinúdá ti wà nílê wa ÿaájú kí òyìnbó tó gbé tirê dé.

Àwôn onímõ mìíràn bí Òjó (2013), Information Palour (2015), Facts.Ng (2017), Encyclopedia.Com (2003) gbà pé õnà ìbánisõrõ abínibí ni àrokò pípa jë.

Tíörì

Tíörì tí a fi ÿe òpó iÿë yìi ni tíörì ìbára-çni-ÿe-põ alárokò (Symbolic Interactionist Theory). Gëgë bí Hannan (2019) ÿe sô nínu iÿë rê tó pè ní Symbolic

Page 3: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

166

Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé Interactionist Theory, tíörì yìí jë êyà kékeré kan lára

tíörì ìbára-çni-gbé-põ (sociological theory). Ohun tí tíörì yìi þ sô ni pé ètò ìbára-çni-sõrõ, tí ó pè ní ‘pàsípààrõ ìtumõ látàrí èdè àti àwôn àrokò’ jë õnà kan tí àwôn ènìyàn àwùjô fi máa þ bá ara wôn ÿe. Herman àti Reynolds (1994) wòye pé ìlànà yìí máa þ rí àwôn ènìyàn bí pé wôn þ kó ipa pàtàkì nínú bí àwùjô alájôÿepõ wôn yóò ti ÿe rí, dípò kí àwùjô máa lò wön mö ìgbà tàbí máa rô wön.

George Herbert Mead (1863-1931) ni àwôn onímõ gbà gëgë bí olùdásílê tíörì ìbára-çni-ÿe-põ alárokò, bó tilê jë pé òun fúnra rê kò ní àýfààní láti tç iÿë rê jáde lórí tíörì yìí (LaRossa and Reitzes, 1993). Akëkõö Mead kan tó þ jë Herbert Blumer ló rô orúkô ‘ìbára-çni-ÿe-põ alárokò’ fún tíörì yìí, ó sì ÿe àgbékalê àwôn àbùdá pàtàkì mëta láti ÿe àpèjúwe tíörì náà.

i. Àwôn êdá ènìyàn máa þ ní ìbáÿepõ pêlú àwôn ohun èlò látàrí àwôn ìtumõ tí a fún wôn.

ii. Ìtumõ tí a fún àwôn ohun èlò wõnyí máa þ jç yô látàrí ìbáÿepõ pêlú àwôn ènìyàn mìíràn àti àwùjô lápapõ.

iii. Àwôn ènìyàn máa þ fún àwôn ohun èlò wõnyí ní ìtumõ ní ìbámu pêlú àsìkò àti õgangan ipò tí a ti lò wön (Blumer, 1969).

Àpççrç tí Blumer fi ÿe àpèjúwe ni pé àwôn ohùn èlo tí a fi þ pa àwôn àrokò wõnyí kò ní ìtumõ kan pàtó, àmö àwôn ìbára-çni-ÿe-põ tí a ti ní pêlú ara wa, ni a fi þ fún àwôn àrokò náà ní ìtumõ tó jë ìtëwögbà fún gbogbo àwùjô. Nínú iÿë yìi, a rí êrí náa lára àwôn tó þ ÿe àmulo àwôn oríÿiríÿi ohun èlò fún àrokò pípa, bóyá ti àtijö ni (bí

Page 4: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

167

The 9 No. 4)

owó çyô, ìlêkê, çyin adìyç, abbl) tàbí ti ìgbàlódé (bí àwòrán orí êrô ayélujára bí òdòdó, nýkan àÿírí ômônìyàn, àmì ìfçnukonu, ìfë, abbl). Þÿe ni àwôn olùpàrokò þ wòye àwôn ohun èlò tó tö lati pàrokò látàrí èrò ôkàn wôn, tí àwôn olùgbàrokò náa sì þ lo õgangan ipò tí àwôn àrokò náa gbà wá láti fún wôn ní ìtumõ. Látàrí ìbára-çni-ÿe-põ tó þ wáyé láàrin àwôn ènìyàn àwùjô ni àwôn ìtumõ wõnyí ÿe þ di ìtëwögbà, tí àwôn ìtumõ náà sì þ di kárí-àwùjô (https://courses.lumenlearning.com/alamo-sociology/chapter/reading-symbolic-interactionist-theory/). Orísun Àrokò

Nígbà tí Ajétúnmôbí (2014) sô pé õdõ àwôn ìran Yorùbá ni ìlànà ìbánisõrõ yìí ti ÿê, Okeke, àti Chukwu (2017) jë ká mõ pé kì í ÿe àwôn ìran Yorùbá nìkan ni wön máa þ pa àrokò. Àmö ju gbogbo rê lô, a kò rí onímõ kan tó tako àbá pé õnà ìgbàbánisõrõ ni àrokò pípa jë. Gbogbo àwôn onímõ wõnyí ló gbà pé àÿírí ni ìtumõ àrokò máa þ jë. Àti pé löpõ ìgbà ìránÿë àrokò kì í mô ìtumõ àrokò tàbí ohun tó wà nínú àrokò tí wön fi rán òun níÿë. Àwôn Ikõ Àrokò

Òjó (2013) àti Information Parlour (2015) wá gbà pé àwôn ikõ mëta ló máa þ rõ mö àrokò pípa. Àwôn náà ni olùpàrokò, ìránÿë àrokò àti ohun èlò tí a fi pa àrokò náà. Eléyìí lè má rí bëê tí a bá fi iÿë gbajúgbajà Shannon a ti Weaver (1949) àti Ayõdélé àti Adéníyì (1999) wo àwòÿe ìbánisõrõ (communication model). Õnà mërin ni a óò pín àwôn ikõ àrokò sí. Àwôn mërêêrin náà ni;

Page 5: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

168

Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé olùpàrokò, ìránÿë àrokò, ohun èlò tí a fi pa àrokò àti

olùgbàrokò. A lè ÿe àpèjúwe wôn pêlú àwòrán atöka ìsàlê yìí.

Olùpàrokò ìránÿë àrokò ohun èlò olùgbàrokò Àwôn Àyípadà tó Dé Bá Àrokò Pípa Lóde òní

Õpõlôpõ àwôn àyípadà ló ti dé bá àrokò pípa lóde òní. Lákõökö ná, ìfàsëyìn þlá ti bá àrokò pípa ní ìlànà àdáyébá. Lára àwôn ohun tó ÿokùnfà àwôn ìfàsëyìn wõnyí ni; ìdàgbàsókè ìmõ êrô, õlàjú ilê òkèèrè, êsìn àtõhúnrìnwá, abbl.

Ní ìdàkejì êwê, a kò lè sô pé ìfàsëyìn ni àwôn ohun tí àwôn atöka wõnyí kó bá àrokò pípa. Ohun tí a lè sô ni pé, ôpön ti sún, ìmõ ìjìnlê sì ti rewájú. Bó ÿe jë pé ìgbà laÿô, ìgbà lêwù, ìgbà lòdèrée-kókò nílé Ìlôrin, bëê gëgë ló ÿe jë fún õrõ àrokò pípa lóde òní. Þÿe ló wá jë pé aÿô ìgbà ni à þ dá fún ìgbà báyìí. Ìdàgbàsókè þlá ti bá àrokò pípa lóde òní. Níbi tí ìdàgbàsókè õhún gàga àrà dé, þÿe ló dà bí àgbàrá òjò tó þ wö yanrìn, tó sì þ yagi oko lô. Àràbà àwôn õdö òní gbôdõ lô túnra mú, kí odò má baà gbé arère wôn lô, gëgë bó ti ÿe þ gbé àrokò pípa ní ìlànà àdáyébá lô lónìí, mö àwôn baba wa löwö. Wô n gbôdõ lô wá ìmõ kún ìmõ lórí ìÿàmúlò ìmõ êrô fún gbogbo àwôn ohun tí a bá þ ÿe lóde òní. Bí bëê kö, àwôn ômô tí wôn þ bí wõnyí yóò gbé wôn tà pêlú àrokò pípa ní ìlànà ti ìgbàlódé. Ohun tí èyí túmõ sí ni pé, ìmõ ìjìnlê sáyëýsì àti ti êrô ló jë òpómúléró àrokò pípa lóde òní, a sì gbödõ gbájú mö ôn ni.

Page 6: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

169

The 9 No. 4)

Àwôn Atöka Ìlôsíwájú Àrokò Pípa

Gëgë bí Òjó (2013:50) ÿe sô “the influence of Àrokò as a channel of communication has been eroded as a result of modern means of transportation and communication….” Ohun tí Òjó þ sô níbí ni pé, àwôn ìlànà ìgbòkègbodò ôkõ àti ìbánisõrõ òde-òní ti mú kí àdínkù bá ìlò àrokò pípa gëgë bí ìlànà ìbánisõrõ. Àwa rí àwôn ohùn tó töka sí wõnyí gëgë bí àwôn ohun tí a lè sô pé wön mú ìlôsíwájú dé bá àrokò pípa lóde òní. 1. Ilé Ìfìwéránÿë (Postal Services) Tí a bá wo ipa tí àwôn ilé iÿë ìfìwéránÿë þ kó lóde òní, a óò rí i dájú pé àrokò pípa ti têsíwájú. Ilé ìfìwéránÿë ìjôba (post office) Nigerian Postal Services (NIPOST) ti wà káàkiri gbogbo àwôn ìpínlê mërêêrìndínlógójì ilê Nàìjíríà báyìí. Àwôn ènìyàn lè kô lëtà ránÿë síra wôn, kí wön sì tún dá èsì padà pêlú. Bí a bá wá sô pé àwôn ilé ìfìwéránÿë ìjôba wõnyí kò ÿiÿë tó nílê yìí, a tún ti ní àwôn ilé ìfìwéránÿë aládàáni (courier services) bí Fedex RedStar Express, Universal Postal Services (UPS), DHL, abbl. Kì í ÿe lëtà nìkan ni àwôn wõnyí fi þ jíÿë. Àwôn oríÿiríÿi çrù tí a lè dì fún lílò àti pípa àrokò ni àwôn ilé iÿë wõnyí tún fi þ jíÿë pêlú. 2. Ìgbòkègbodò Ôkõ Ìgbòkègbodò ôkõ náà ran àrokò pípa löwö. A ti rí àwôn ilé iÿë ôlökõ èrò ti ìjôba àti aládàáni tí wôn þ báni kó lëtà àti àwôn çrù ránÿë láti ìlú kan sí òmíràn káàkiri ilê Nàìjíríà. Àwôn ilé iÿë ôkõ èrò bí; Kwara Express, Young Shall Grow Motors, Izu Chukwu Transport, ABC Transport Services, God is Good Motors, Peace Mass Transit, abbl ló ti ní àwôn êka tí a ti þ fi lëtà àti çrù

Page 7: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

170

Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé ránÿë síra çni. Ipò ìránÿë àrokò ni wön gbà yìí. Iÿë ajé

tiwôn sì nìyçn. Kódà, àwôn ilé iÿë ìfìwéránÿë aládàáni kan bí; UPS, DHL, IMNL, abbl tún máa þ lo ôkõ òfurufú láti gbé àwôn lëtà àti çrù ránÿë káàkiri àgbáyé. 3. Ìmõ êrô Ìmõ êrô àti ìtànkálê êrô ayélujára tún kó ipa pàtàkì lórí èyí. Lëtà orí êrô ayélujára (e-mail) kó ògo ìfìwéránÿë já. Orí afëfë ni a ti þ fi èyí pàrokò ránÿë síra çni, tó sì þ jíÿë bíi mônawáà. Bákan náà ni ìlò êrô tçlifóònù ìgbàlódé (smart phones) náà tún ÿe ìrànlöwö aláìníye nípa èyí. Ó fërê ë má sìí ohun tí à þ ÿe lórí êrô kõ¸pútà tí àwôn êrô tçlifóònù ìgbàlódé wõnyí kò lè ÿe lórí àrokò pípa àti fífi ránÿë síra çni. Õpõlôpõ àwôn àmì àrokò ló ti þ bá àwôn êrô wõnyí wá. Àwôn ènìyàn sì þ ÿàmúlò wôn láti pàrokò síra çni káàkiri àgbáyé. Kódà, ní ti êrô ayélujára, kò sí irúfë êyà àmì àrokò tí ç fë lò, tí êrô náà kò ní ÿàwárí rê fún yín lórí Google Search, MSN, abbl. Àwôn ìtàkùn ìròyìn törö-fönkálé (social media) tún wá ní kín ló ÿubú tç àwôn nípa ìpèsè àwôn àrokò ìgbàlódé. Ó fërê má sìí irúfë àrokò tí àwôn õdö òní kì í ÿàmúlò lórí ìtàkùn ìròyìn törö-fönkálé Facebook, WhatsApp, Instagram, abbl. Iÿë takuntakun ni êmójì (emoji) àti êmótíköõnù (emoticon) þ ÿe nínú irúfë àrokò yìí. Mëséþjà (Messenger) Gëgë Bí Ìránÿë Àrokò

Àwôn ilé iÿë ayélujára Yahoo, WhatsApp àti Facebook tilê mú iÿë àrokò pípa níbàádà débi pé wön dá ìránÿë àrokò wôn yà sötõ. Orúkô tí wôn þ pe ìránÿë yìí ni mëséþjà (messenger). Mëséþjà yìí ni àwôn olùpàrokò þ lò fún àwôn ìbánisõrõ wôn, ti àwôn olùgbàrokò náà sì fi þ dá èsì padà. Òun ni a sì le pè ní ìránÿë àrokò. Êmójì

Page 8: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

171

The 9 No. 4)

àti êmótíköõnù sì jë ara àwôn abçnugan ìgbìmõ ìÿàkóso àwôn irinÿë ìtàkùn ayélujára yìí. Lëtà kíkô ló ÿìkçta nínú àwôn ìgbìmõ yìí. Òun ló gba ipò abájérìn (official) ju àwôn êmójì àti êmótíköõnù lô.

A lè ÿàmúlò àwôn àrokò ìgbàlódé fún gbogbo àwôn ohun tó rõ mö õrõ ìfë (tó lè padà wá yôrí sí ìgbéyàwó tàbí ìpínyà), ômô bíbí, oyè jíjç, àti àwôn oníranýran õrõ ohun tó þ jç ômô êdá lógún lóde òní. ßùgbön gëgë bí òté, àwôn àrokò tó jç mö õrõ ìfë, ômô bíbí àti oyè jíjë ni àwôn àrokò tí a óò gbájú mö ní ipele yìí.

Àwôn Àrokò Ìgbàlódé Tó Jç Mö Ômô Bíbí: Àwôn àrokò tó jç mö ômô bíbí àti ìtumõ wôn nìwõnyí.

a bímô tuntun. Ç bá wa yõ.

a bí ìbejì làýtìlanti. Ç bá wa yõ.

a bímô tuntun tàbí ômô ìkókó þ jçun löwö.

mò þ fún ômô löyàn, mò þ tömô ìkókó löwö tàbí abiyamô ni mi.

Page 9: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

172

Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

Ilé ìwòsàn ìgbêbí ômô ni èyí þ töka sí. Àwôn Àrokò Ìgbàlódé Tó Jç Mö Õrõ Ìfë: The Yoruba (2017) jë ká mõ pé àwôn Yorùbá máa þ pàrokò ìfë. Ó ní “Aroko was also used of course, in love and friendship.”

(http://www.theyoruba.com/2015/ 12/yoruba-system-of-communication-aroko/). Àwôn àrokò tó jç mö õrõ ìfë ló gbajúgbajà jùlô lóde òní. Àwôn õdömôkùnrin, õdömôbìnrin, adélébõ àti àwôn baálé ilé pàápàá, gbogbo wôn ló þ ÿàmúlò wôn fún ìdí kan tàbí èkejì. Kódà àwôn ìpëêrê àti àwôn màjèsín wa gbogbo ni wôn þ jí àrokò ìfë pa níkõkõ. Àpççrç díê nínú wôn nìwõnyí:

Jë kí á jô máa jáde.

Mo nífêë rç. Jõwö jë kí n máa fë ô.

Mo nífêë rç. Ìfë rç ti ràdõ bò mi/ôfà ìfë rç wô ôkàn mi.

Mo fë fi ö ÿaya (ó sì lè jë mo fë fi ö ÿôkô mi pêlú).

Page 10: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

173

The 9 No. 4)

Ìtôrô aya tàbí jõwö fi mi ÿe adé orí rç.

Ìgbéyàwó Ìgbéyàwó.

Ìpínyà ìfë Ìfçnukonu. Àwôn Àrokò Àlùfàýÿá: Àrokò ìfë tún le pêka sí ti àwôn àrokò àlùfàýÿá. Dípò àtêránÿë, àwôn oni nàbì ènìyàn tún ti jágbön ohun tí a lè pè ní ‘àtêránÿë àgbèrè’. ‘Sexting’ (sexy text messages) ni wôn þ pe èyí (http://www.romanceways.com/100-top-sexting-examples.html). Ó wöpõ láàrin àwôn õdö àti àwôn ìpëêrê wa púpõ. Àfi kí gbogbo òbí sán ÿòkòtò àti tòbí wôn danindanin ni, láti lè ÿàmójútó àwôn õdö ìwòyí. Ohun tí wôn þ dá lárà pêlú àwôn àrokò wõnyí kò dçrùn. Díê lára àwôn àrokò náà nìwõnyí:

Mo fë bá ç ÿeré ìfë. Mo fë muyàn tàbí wá muyàn

Ara mi kún, mo fë jápo fún ç tàbí wá jápo fún mi.

Page 11: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

174

Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

tàbí tàbí Wá bá mi sùn/mo fë bá ç sùn

Okó yìí di tèmi nìkan ÿoÿo. Àwôn Àrokò Tó Jç Mö Oyè Jíjç: Ìsõrí àwôn àrokò wõnyí kò põ púpõ. Ó le jë pé ohun tó fa èyí ni pé çni tó bá jçun yó tán ló þ dámõràn oyè jíjç. Ebi kì í pani débi oyè jíjç, yàtõ sí çni tí wön bá dìídì yàn sóyè, gëgë bi êtö tàbí oyè çnu iÿë. Àti pé, ipò àgbà ni ipò oyè jíjç. Bí olóyè kò bá dàgbà löjö orí, ó ti dàgbà ní ipò torí pé, a gbödõ máa fi õwõ oyè rê wõ ö. Bákan náà, àÿìlò àrokò oyè le kóni sí ìjàngbõn. Ìyçn bí çnìkan bá lô ÿàmúlò àrokò oyè tí kò tö sí i. Nítorí náà, àwôn àrokò oyè jíjç kò pawó wôlé bí ti ômô bíbí àti õrõ ìfë tó kálékáko. Wön máa þ ÿe àmúlò àwôn àrokò wõnyí nínú àwôn ìwé ìpè, ìkéde, ìsôfúnni, abbl. Àwôn àrokò wõnyí lè jë ti oyè àbáláyé, ìjôba, iÿë tàbí êsìn. Àrokò ìdánimõ ni wön sì máa þ sáábà jë pêlú.

Àwôn Àrokò Oyè Ìgbàlódé: Yàtõ sí àwôn oyè àbáláyé tí à þ fi àwôn nýkan bí; adé ôba, õpá ìlêkê, ìlêkê ôwö àti ti ôrùn, çdan ògbóni àti àwôn mìíràn pàrokò wôn, a tún ti ní àwôn oyè ìgbàlódé. Lára àwôn oyè ìgbàlódé ni oyè ìjôba, oyè iÿë àti oyè êsìn-àtõhúnrìnwá.

Page 12: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

175

The 9 No. 4)

Àwôn Àrokò Oyè Ìjôba: Õwõn orílê-èdè Nàìjíríà (the Nigerian Coat-of-Arms) ni pàtàkì jùlô nínú àwôn àrokò oyè ìjôba (Mustapha 199194). Àwôn aÿíwájú olóÿèlú bí ààrç orílê èdè, gómìnà, àwôn igbákejì wôn, alákòóso ile iÿë ôba, àwôn aÿòfin, õgá lënu iÿë ôba, kábíyèsí, àwôn ìjòyè pàtàkì, abbl., ni wön máa þ ÿàmúlò rê láti júwe ara wôn. Ó le wà nínú káàdì ìpolówó ajçmöÿë (official complimentary card) wôn. Wön lè gbé àwòrán õwõn yìí sára ôkõ ayökëlë wôn. Wön tún máa þ ya àwòrán rê sára àwôn ìwé ìpè tó bá jç mö ti ipò wôn, lára àga ìjókòó inú ôkõ, ti öfíìsì, abbl. Kódà ààrç, gómìnà àti àwôn igbákejì wôn máa þ ya àwòrán rê sí ara àpótí ìbánisõrõ (dais) wôn. Òté (seal) lorúkô tí wön sáábà máa þ pè é, ní gbogbo ìgbà tí wön bá þ ÿàmúlò rê. Õràn þlá ni fún çni tí kò lêtöô láti lo àrokò yìí láti ÿàmúlò rê (http://www.nigeria-law.org/Criminal%20Code%20Act-Tables.htm).

Díê lára àwôn àrokò tó jç mö oyè ìjôba nìwõnyí:

Àwôn aÿíwájú olóÿèlú bí ààrç, gómìnà, àwôn igbákejì wôn, alákòóso ilé iÿë ôba, àwôn aÿòfin, õgá lënu iÿë ôba, kábíyèsí, àwôn ìjòyè pàtàkì, abbl.

Ààrç orílê èdè Nàìjíríà Igbákejì ààrç orílê èdè

Gómìnà ìpínlê Igbákejì gómìnà ìpínlê

Page 13: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

176

Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé Àwôn Àrokò Oyè Iÿë

Õkan pàtàkì lára àwôn àrokò oyè jíjç ni èyí náà. Ó máa þ jë ìdánimõ fún olùpàrokò. Àÿç gbödõ wá láti õdõ àwôn aláÿç kan pàtó, kí òÿìÿë tó lè ÿàmúlò àrokò yìí láti júwe ara rê. Àwôn ôlöpàá (The Nigeria Police), jagunjagun orí ilê (Nigerian Army), orí omi (Nigerian Navy), ti ojú òfurufú (Nigerian Air Force), Êÿö Àrìnyè (Federal Road Safety Corps), Êÿö Aÿöbodè (Nigerian Customs), Êÿö Wôléwõde (Nigeria Immigrations Service), Êÿö Aláàbò Ìlú (Nigerian Civil Defence Corps), abbl. jë àpççrç àwôn òÿìÿë ìjôba tó máa þ lo àwôn àrokò wõnyí láti ÿàpèjúwe oyè wôn. Àwôn òÿìÿë ààbò aládàáni náà máa þ lo àwôn àrokò oyè wõnyí. Àpççrç irúfë àwôn ilé iÿë aláàbò bëê ni Proton Guards, TechnoCrime Security Nigeria limited, Synergy Guards Nigeria, Halogen Security, abbl (http://nigerianfinder.com/10-best-security-companies-in-nigeria/).

Ohun tó kàn ya àwôn òÿìÿë ààbò aládàáni sötõ pêlú àwôn òÿìÿë aláàbò ìjôba ni pé, àrokò oyè ti àwôn agbèföba wõnyí ÿõkan, wön ÿe é dá mõ káàkiri àgbáyé, õwõ àti àpönlé sì wà fún wôn pêlú. Ní ti àwôn òÿìÿë ààbò aládàáni, kò si ìÿõkan nínú àwôn àrokò oyè wôn. Àrokò oyè ti Proton Guards yàtõ sí ti Halogen Security, ti TechnoCrime Security Nigeria Limited yàtõ sí ti Synergy Guards Nigeria, abbl. Nítorí náà, wön ÿòro láti mõ fún çni tí kò bá nímõ nípa àwôn àrokò oyè wôn. Bákan náà, õwõ àti àpönlé tó wà fún àwôn àrokò oyè náà kò kôjá inú agbègbè ibi tí ôwöjà ààbò wôn bá dé àti láàrin àwôn òÿìÿë wôn.

Page 14: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

177

The 9 No. 4)

Àpççrç Àwôn Àrokò Oyè Jíjç Lënu Iÿë

Àrokò àwôn àjô Ôlöpàá ilê Nàìjíríà (The Nigeria Police) ni a óò fi ÿe òpó àpèjúwe wa lábë ìsõrí yìí. Díê lára wôn nìwõnyí:

Köbùrù (Corporal) Sájëýtì (Sergeant)

Rìpëtõ (Inspector) Kômísönnà (Commissioner)

Rìpëtõ Jënërà (Inspector General) Àwôn Àrokò Oyè Êsìn Àtõhúnrìnwá

Àwôn êsìn Mùsùlùmí àti ti Ômôle yìn Kírísítì ló léwájú nínú àwôn êsìn àtõhúnrìnwá nílê Yorùbá lode-òní. Àwôn êsìn méjéèjì ló ní àwôn oyè wôn. Àrokò pípa sì wà láti dá àwôn oyè náà mõ pêlú.

tàbí Àlàájì/Àlàájà fún ôkùnrin/ obìnrin Mùsùlùmí

Lèmömù àti làdánì. Pásítõ, ajíyìnrere, abbl.

Bíÿöõbù. Póòpù.

Page 15: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

178

Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé Gbogbo àwôn àrokò oyè wõnyí ni à þ fi êrô

kõýpútà àti àwôn êrô ìbánisõrõ igbalode gbé jáde lórí àwôn êrô ayélujára àti ìtàkùn ìbánidörêë gbogbo.

Ìyàtõ Láàrin Àwôn Àrokò Àtijö àti ti Ìgbàlódé

1. Àwôn àgbàlagbà (tí ôjö orí àti ipò) lo põ jù nínú àwôn tó þ ÿàmúlò àrokò ayé àtijö. Àwôn õdö ló põ jù nínú àwôn tó þ ÿàmúlò àrokò ìgbàlódé. Kódà bó ÿe àrokò ìdánimõ oyè jíjç, torí pé çnikëni tó bá ti pé ômô ôgöta ôdún nílê yìí gbödõ fêyìntì lënu iÿë ìjôba (http://www.lawnigeria.com/LawsoftheFederation/STATUTORY-CORPORATIONS-PENSIONABLE-OFFICERS-(RETIRING-AGE-LIMIT)-ACT.html).

2. Àwôn àgbà ló þ mô ìtumõ àwôn àrokò ayé àtijö ju àwôn õdö lô. Àwôn õdö ló mô ìtumõ àrokò ìgbàlódé ju àwôn àgbà lô.

3. Wôn kì í déédé ÿàmúlò àwôn àrokò ayé àtijö. Ó gbödõ ní ìdí pàtàkì, kí wön tó le pàrokò. Fún õpõlôpõ àwôn õdö, ohun ìgbafë tàbí ìdárayá ni àrokò pípa jë lórí ìtàkùn ìròyìn törö-fönkálé. Ìgbàkugbà tí ôwö wôn bá dilê, ohun tí wön fi þ dárayá nìyí.

4. Aÿènìyàn ni ìránÿë àrokò máa þ jë. Êrô tàbí àwôn ohun aláìÿènìyàn mìíràn ni ìránÿë àrokò máa þ jë ní õpõ ìgbà.

5. Ó máa þ pë díê kí àrokò ìbánisõrõ tó dé õdö olùgbàrokò. Èsì dídápadà náà a máa löra nílê díê pêlú. Níÿêëjú àáyá ni àrokò máa þ kan olùgbàrokò lára (bí kò bá si ìdíwö kankan). Dídá èsì padà náà a

Page 16: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

179

The 9 No. 4)

máa yá kánmökánmö. Kódà àrokò pípa àti èsì dídápadà lè máa têlé ara wôn ní kõsçkõsç.

6. Àwôn ohun àrídìmú ni wön sáábà máa þ lò láti pàrokò ìbánisõrõ láyé àtijö. Àwôn ohun èlò àfojúrí lásán (tí wön máa þ jë afòyemõ yàtõ sí àrídìmú) ló põ jùlô nínú àwôn ohun èlò àrokò ìgbàlódé.

7. Àwôn àrokò wõnyí kò lësê nílê, gëgë bí êrí nílé çjö. Bí àpççrç, ó ÿòro kí obìnrin tó le fìdí rê múlê nílé çjö pé ôkùnrin kan kôlu êtö òun látàrí pé ó fi orín ránÿë si òun, tó sì mõ pé abilékô lòun tàbí lëyìn tí òun ti kìlõ fún un pé nýkan bëê kò të òun lörùn. Àwôn àrokò wõnyí fçsê múlê danin gëgë bí êrí nílé çjö. Ìdí ni pé, ó rôrùn láti pe àrokò ìbánisõrõ ìgbàlódé orí ìtàkùn ìròyìn törö-fönkálé tàbí lëtà ayélujára jáde lórí êrô, kí wön ÿe àyêwò rê, kí wön sì rí àwôn àkôsílê tó bá àrokò náà lô. Àpççrç irúfë eléyìí ni çni tó fi àmì ìfçnukonu ránÿë sí abilékô lórí ìtàkùn ìbánidörêë, lëyìn tí àrídájú ti wà pé ó mõ pé irúfë obìnrin náà kì í ÿe wúþdíá tàbí ômôge, bí kò ÿe abilékô (http://www.cknnigeria.com/2013/07/i-had-oral-sex-with-my-rock-insurance.html). Eléyìí ni Romanceways.com (2013) rí tó fi sô pé, “you should know the person you are sexting to, very well. Make sure you can trust him/ her because a sext can always be forwarded”. (http://www.romanceways.com/100-top-sexting-examples.html).

Page 17: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

180

Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé 8. Ìdíwö lè wà fún àrokò ìbánisõrõ láti dé õdõ

olùgbàrokò. Bi àpççrç, òpin lè dé bá ìránÿë àrokò lönà ìrìnàjò láti fi àrokò jíÿë kó má lè gbé àrokò náà débi tí a rán an sí. Olùpàrokò lè má mô èyí. Yóò máa lérò pé àrokò òun ti débi ti òun fi ránÿë sí. Olùgbàrokò náà kò sì ní mõ pé wön ti fi àrokò õhún ránÿë sí òun pêlú. Bí ìdíwö kan bá ÿçlê, ó rôrùn fún olùpàrokò láti tètè mô èyí. Bí kò bá sì mõ, ó rôrùn fún un láti ÿèwádìí lödõ olùgbàrokò, kó sì fi òmíràn ránÿë, bó bá yç bëê.

9. Àrokò ìbánisõrõ àtijö máa þ náni lówó àti wàhálà púpõ láti fi ránÿë. Ààbò êmí kò dájú púpõ lórí ìránÿë àrokò. Owó péréte ni àrokò ìbánisõrõ ìgbàlódé máa þ náni, bí a bá ÿàfiwé wôn pêlú ti ayé àtijö. Ewu çranko búburú, àwôn onísùnmõmí àti ìbínú olùgbàrokò kò la ewu lô fún ìránÿë àrokò.

10. Ó rôrùn láti fi ojú àbùkù wo àrokò ayé àtijö púpõ. Bi àpççrç, owó çyô mërin tó kô êyìn sí ara wôn nínú àwôn àpççrç Òjó, MOD (2013:55) lè dà bí ñýkan çbô lójú olùgbàrokò, bí a bá fi ránÿë síni gëgë bí àrokò lóde òní. Bí olùgbàrokò kò bá tún wá mô ìtumõ àrokò náà, ó ÿe é ÿe kó máa sáré kiri möÿálááÿí tàbí ÿöõÿì fún ìgbàlà kúrò nínú ète õtá. Àpönlé wà fún eléyìí ju ti àtijö lô. Çni tí a fi owó çyô méjì ránÿë sí lórí ìtàkùn ìròyìn törö-fönkálé sì lè máa rí i bí ìgbà tí a fë fún òun lówó tàbí ÿàdúrà ìbùkún owó fún òun. Tó bá tún wá mô ìtumõ àrokò náà sí ti õrõ ìfë, kò ní dààmú kankan, bí

Page 18: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

181

The 9 No. 4)

èròýgbà olùpàrokò kò bá tilê të ç lörùn. Àti pé õtõ ni ìtumõ tí owó çyô méjì tó dojú kôra wôn yóò ní, bí a bá fi ránÿë síni lórí ìtàkùn ìbánidörêë.

Ìjôra Láàrin Àrokò Ayé Àtijö àti ti Ìgbàlódé

Àwôn ohun tó pa àrokò ayé àtijö àti ti ìgbàlódé põ nìwõnyí: 1. Ìlànà ìbánisõrõ ni àwôn méjéèjì. A sì tún lè ÿàmúlò

wôn gëgë bí àrokò ìdánimõ pêlú. 2. Àwôn oríÿìí àrokò méjéèjì ló þ kó ipa pàtàkì nínú

àlàáfíà, ìfõkànbalê àti ìlôsíwájú ìlú. Níbi tí wön bá ti pàrokò ìfë ránÿë, tí àwôn olùgbàrokò náà sì þ fara mö ôn, ó di dandan kí eléyìí ran ìbáÿepõ àwôn ará àwùjô löwö, kí ó sì máa ÿe ìtànkálê àlàáfíà àti ìlôsíwájú àwùjô.

3. Bí àrokò pípa bá sì lô gbòdì, ó lè fa dúkùú, àìgböraçniyé, ìdàrúdàpõ, hílàhílo àti ìfàsëyìn bá àwôn àwùjô wa. Irú àpççrç abilékô tí wön pa àrokò àlùfàýÿá fún, àti àwôn oríÿìí àpççrç mìíràn tí ààyè kò sí fún wa tó láti máa töka sí, gbogbo wôn ló lè dá ogun sílê kó sì fa ìfàsëyìn bá àwùjô.

4. Àwôn ikõ mërêêrin tó þ kópa nínú àrokò pípa gbödõ pé nínú àwôn oríÿìí àrokò méjéèjì. Kódà nínú àrokò ìdánimõ pêlú, olùpàrokò ni çni tó þ ÿàpèjúwe ara rê (b.a. sájëýtì ôlöpàá), olùgbàrokò ni àwôn tó þ júwe ara rê fún (ará ìlú), ìránÿë àrokò ni ohun èròjà tí wön pa àrokò náà sí lára (aÿô iÿë), àmì ìdánimõ rê gan-an ni ohun èlò àrokò (àmì sájëýtì apá rê).

Page 19: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

182

Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé Ìwúlò àrokò pípa lórí êkö èdè Yorùbá

Tí àwôn õdö àti ômôdé òde-òní bá þ ÿàmúlò àrokò pípa lönà tó dára, àýfààní põ níbê fún êkö èdè. Lára àwôn àýfààní bëê ni: 1. Êkö nípa pípa àrokò yóò sô àwôn akëkõö di ôlôgbön

àti olóye. Dípò kí wôn máa fi gbogbo çnu sõrõ, þÿe ni wôn yóò máa sõrõ lówelówe pêlú àrokò.

2. Àrokò pípa yóò dáàbò bo èdè látàrí ÿíÿô õkan pàtàkì lára àwôn àÿà wa löjõ. Tí àÿà kò bá parë, ikú ti yê lórí èdè náà nìyçn.

3. Pípa àrokò lórí àwôn ìtàkùn ìròyìn törö-fönkálé wõnyí yóò jë kí á lè ÿàmúlò ìmõ êrô láti gbé èdè àti àÿà lárugç. Èyí yóò sì ÿe ìgbélárugç púpõ fún èdè torí pé ibi ìlò ìmõ êrô ni ayé tê sí báyìí.

Àbá

Bí a àwa olùkö bá túbõ kö êkö nipa ÿiÿë àmúlò àrokò orí êrô ayélujára gëgë bí ohùn èlò ìköni ní àwôn ilé-ìwé alákõöbêrê àti girama, tí a sì n ÿàmúlò àwôn àrokò ìgbàlódé láti máa kö àwôn ômô lëkõö ní àwôn ilé-ìwé wa gbogbo, eléyìí yóò je ki kíkö àwôn ômô lëkõö máa rôrùn púpõ sí i. Bí àwôn ômô wõnyí ÿe þ kö êkö, ni àwôn àrokò wõnyí yóò tún máa dá wôn lára yá pêlú. Ìjôba àti àwôn olùdásílê ilé-êkö aládàáni ní ipa pàtàkì láti kó lórí èyí. Kí ìjôba ÿe àwôn òfin kàn-án-þpá lórí èyí, kí àwôn àti àwôn olùdásílê ilé-êkö aládàáni sì ró àwôn olùkö wôn lágbára látàrí ÿíÿe ìrànwö ìgbêkö nípa lílo êrô ayélujára fún wôn.

Page 20: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

183

The 9 No. 4)

Ìkádìí

Ohun tí a rí nínú ìwádìí yìí ni pé õnà ìgbàbánisõrõ tó gbòòrò ni àrokò pípa jë. Gëgë bí àwôn àÿà ilê Yorùbá kò ÿe dúró sójú kan, ni àrokò pípa náà ti têsíwájú. Êrô ayélujára ti wá sô àrokò pípa di ohun tó lárinrin, tó múnádóko, tó sì mú ìgbélárugç bá êkö èdè àti ìdájö òdodo láwùjô wa ní òde òní. Àwôn òbí àti alágbàtö gbödõ sán ÿòkòtò àti tòbí wôn dáradára, kí àwôn ômô wa má baà rì wön sínú agbami àrokò ìgbàlódé tó þ fojoojúmö gbìnàyá sí i. Ó wá ÿeni láàánú pé bí ìlôsíwájú ÿe þ bá àrokò ìgbàlódé, ni iná àrokò àbáláyé þ jó àjórêyìn. Eléyìí jë ara ohun tí Ajétúnmôbí kíyèsí tó ÿe dábàá pé, a níláti wá õnà láti gbé ìmõ nípa êkö àrokò àbáláyé wô inú kõríkúlöõmù àwôn ilé ìwé wa gbogbo, kí ìmõ yìí má baà di ohun ìtàn. Bí bëê kö, gbogbo çnu la lè fi sô ö pé àrokò pípa ti kúrò löwö àwôn àgbà, ó sì ti bö sí ôwö àwôn õdö. Bákan náà, lílo àrokò gëgë bí ohùn èlò ìköni ní àwôn ilé ìwé wa, kí wön lè máa ÿàmúlò àrokò ìgbàlódé láti máa kö àwôn ômô lëkõö ní àwôn ilé ìwé wa gbogbo yóò ran ètò êkö löwö. Ìmõ yóò máa rewájú, àlàáfíà àwôn ômô yóò máa lé kún, ôrõ ajé àwùjô náà yóò sì máa gbèrú sí i. Ìwé Ìtökasí

Adéoyè, C.L. (1980). Àÿà àti Ìÿe Yorùbá: Ibadan: University Press Plc.

Ayõdélé, A. and Adéníyì H. (ed.) (1999). Language and Communication (an introductory text vol. 1). Lagos, Nigeria: Harade Publishers.

Page 21: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

184

Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé McQuail, Dennis (2010), McQuail’s Mass Communication

Theory, 6th Edition, London, United Kingdom: Sage Publications Ltd.

Mustapha, O.; Oye de mi , O.; Àlàgbe , A. àti Ade bo wa le , O. (1991). Êkö Èdè Yorùbá Titun (SSS) Ìwé Kçta; University Press Plc; Ibadan, Nigeria

Mustapha, O.; Oye de mi , O.; Àlàgbe , A. àti Ade bo wa le , O. (1991). Êkö Èdè Yorùbá Titun (SSS) Ìwé Kejì; University Press Plc; Ibadan, Nigeria

Ìwé Ìtökasí Lórí Êrô Ayélujára

Adelu, A and Ayedun-Aluma, V in Maifitila (2015): The Àrokò Code. A publication of the Africa’s Communication Heritage Journal retrieved on 21st December, 2017 at http://maifitila.blogspot.com.ng/ 2015/11/the-aroko-code.html

Ajétúnmôbí, R.O. (2014). Indigenous Knowledge and Communication Systems – The Case of Yoruba Aroko. Retrieved on 28th, November, 2017 via http://www.nairaland.com/1829695/aroko-yoruba-hieroglyphics

CKN News (2018), I had Oral Sex With My “Rock Insurance” Boss.. Housewife Admits. A publication of CKN News Nigeria, retrieved on 4th January, 2018 at http://www.cknnigeria.com/2013/07/i-had-oral-sex-with-my-rock-insurance.html

Facts.ng (2017): Naming Ceremony (Iso Omo Loruko) retrieved on 19th December, 2017 at https://www.facts.ng/culture/naming-ceremony-iso-omo-loruko/

Hannan, P (2019), in Lumen Learning. Reading: Symbolic Interactionist Theory retrieved on 20th March, 2019 via

Page 22: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

185

The 9 No. 4)

https://courses.lumenlearning.com/alamo-sociology/chapter/reading-symbolic-interactionist-theory/

Information Parlour (2017), Communication System. Retrieved on 19th December, 2017 at http://informationparlour.com/article-culture-tradition-communication-system-ancient-yoruba-culture

LawNigeria.Com (2017), the Statutory Corporations Pensionable Officer (Retiring Age Limit) Act, published by LawNigeria.Com (Independent Clearing House for Nigeria’s Justice Sector. Retrieved on 8th January, 2018 at http://www.lawnigeria.com/ LawsoftheFederation/STATUTORY-CORPORATIONS-PENSIONABLE-OFFICERS-(RETIRING-AGE-LIMIT)-ACT.html

Nigeria-Law.Org (2017), Criminal Laws Code Act 77 Laws of The Federation of Nigeria 1990. A publication of Nigeria-Law.Org, retrieved on 8th January 2018 at http://www.nigeria-law.org/ Criminal%20Code%20Act-Tables.htm

Nigerian Finder (2017), 10 Best Security Companies in Nigeria. Retrieved on 8th January, 2018 at http://nigerianfinder.com/10-best-security-companies-in-nigeria/

Òjó, M.O.D. (2013). Symbols of Warning, Conflict, Punishment And War And Their Meanings Among The Pre-Colonial Yoruba Natives: A Case Of Aroko retrieved on 20th December, 2017 at http://www.anthroserbia.org/Content/PDF/Articles/b5303c523d714278a03219fe82158d7f.pdf

Page 23: Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö- fönkáléysan.org/umgt/uploaded/10-Ju19-Aroko pipa lori awon...166 Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé

186

Àrokò Pípa Lórí Àwôn Ìtàkùn Ìròyìn Törö-fönkálé Òkéke, A.F. and Chukwu, K.C. (2017). Language Use In

Communication: A Semiotic Perspective On Select Igbo Cultural- Symbolic Objects. Retrieved on 20th December, 2017 at journals.ezenwaohaetorc.org/ index.php/AJLLS/article/download/201/134

Romanceways.com (2013), 100 Top Sexting Examples. Retrieved on 10th January 2018 at http://www.romanceways.com/100-top-sexting-examples.html

The Yoruba (2017), Àrokò, Retrieved on 28th, November, 2017 via http://www.theyoruba.com/2015/12/yoruba-system-of-communication-aroko/